Adamu: Olùkọ̀ 2,295 ni Boko Haram pa láàárín ọdún mẹ́sán

Obinrin kan n daro pẹlu omije loju Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Àwọn olùkọọ́ tí orí kó yọ ti fọ́n káàkiri àwọn ìpínlẹ̀ Yobe, Borno àti Adamawa

Ǹjẹ́ o mọ̀ pé Olùkọ́ tó lé ni ẹgbẹ̀rún méjì ló ti kú sínú làásìgbò ìkọlù Boko Haram lẹ́kùn ìlà oòrùn àríwá Nàíjíríà?

Mínísítà fétò ẹ̀kọ́ lórílẹ̀-èdè Nàìjíríà, Adamu Adamu, ló ṣàlàyé èyí níbi ìdánilẹ́kọ̀ọ́ lórí ààbò níléèwé tó wáyé nílùú Abuja.Mínísítà Adamu Adamu, tó kọminú lórí bí àwọn agbébọn ṣe ń dojúkọ ètò ẹ̀kọ́, ṣàlàyé pé ẹgbẹ̀rún méjì ó lé márún dín lọ́ọ̀dúnrún olùkọ́ ní àwọn agbébọn Boko haram ti pa, tí ẹgbẹ̀rún mọ́kàndínlógún míràn sì ti fọ́n káàkiri àwọn ìpínlẹ̀ Yobe, Borno àti Adamawa láàárín ọdún mẹ́sán sẹ́yìn.

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Ìjọba àpapọ̀ ní òun ń sa ipá gbogbo láti wawọ́ ìkọlù iléèwé bọlẹ̀

Mínísítà fétò ẹ̀kọ́ ni yàtọ̀ sí èyí, ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀jọ iléèwé làwọn agbébọn Boko Haram ti bà jẹ́ láàrín ọdún 2014 sí àsìkò yìí.O ní orílẹ̀-èdè Nàíjíríà ti làkàkà láti wá nǹkan ṣe sí ìpèníjà yìí bii fífọwọ́sowọ́pọ̀ pẹ̀lú àwọn àjọ aṣèrànwọ àti alátìlẹ́yìn gbogbo láti ríi pé ààbò wà fún àwọn akẹ́kọ̀ọ́, olùkọ́ àti iléèwé lẹ́kùn náà.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí: