Ṣé ọgbọ́n fífi ẹjọ́ falẹ̀ kọ́ ni àìsàn olóṣèlú Nàìjíríà?

Aworan Dino Melaye Image copyright Twitter/Dino Melaye
Àkọlé àwòrán Ọrọ kìí sé lẹ́yìn alábahun Dino Melaye

Láìpẹ́ yìí ni iléèṣẹ́ ọlọ́pàá Nàìjíríà gbé aṣòfin Dino Melaye lọ sílé ẹjọ́.

Bi ó tilẹ̀ jẹ́ pé orí ibùsùn aláìsàn ló wà lásìkò nàá, èyí kò dáwọn dúró láti gbé aṣòfin nàá, tí wọn fẹ̀sùn ìwà ọ̀daràn kàn lọ síwájú ilé ẹjọ́.

Image copyright Salleh Ashaka
Àkọlé àwòrán Ilé ẹjọ́ Kogi fi Dino Melaye sí àhàmọ́ títí dí ọjọ́ ìgbẹ́jọ́

Ṣùgbọ́n Melaye kọ́ ni olóṣèlú Nàìjíríà tí yóò kọ́kọ́ lọ sílé ẹjọ́ lórí àketè àìsàn.

Olisah Metuh nàá ṣe bẹ̀ ẹ́

Olisah Metuh, tó ti fìgbàkan jẹ́ akọ̀wé ìpolongo gbogboogbò fún ẹgbẹ́ òṣèlú Peoples Democratic Party, PDP, farahàn nílé ẹjọ́ gíga tìjọba apapọ̀ nílùú Abuja, lọ́jọ́ karùn ún, oṣù Kejì, 2018 lórí kẹ̀kẹ́ aláàrẹ̀, lásìkò tó lọ fún ìgbẹ́jọ́ ẹ̀sùn gbígba irinwó mílíọ́nù Naira láti ọ́ọ̀físì olùgbani nímọ́ràn lóri ètò àábò gbogboogbò lọ́dún 2014, ṣáàjú ètò ìdìbò gbogboogbò tó wáyé lọ́dún 2015.

Èyí mú kí onídàjọ́ Okon Abang, sún ìgbẹ́jọ́ rẹ̀ sí ọjọ́ mì í.

Femi Fani-Kayode nàá kò gbẹ́yìn

Ẹlòmìí tó tún ti ṣe bẹ̀ ẹ́ ni mínísítà fún ìgbòkè-gbodò ìrìnnà ojú òfurufú, Femi Fani-Kayọde, lásìkò tí agbẹjọ́rò rẹ̀, Norrison Quakers, sọ nílé ẹjọ́ lọ̀jọ́ kọkàndínlọ́gbọ̀n, oṣù Kínní, 2018, pé oníbàárà òun kò lè wá fún ìgbẹ́jọ́ nítorí àìsàn tó ní i ṣe pẹ̀lú ọkàn.

Image copyright Femi Fani-Kayode/ Facebook
Àkọlé àwòrán Ẹ̀sùn ìwà ìbàjẹ́ ni àjọ EFCC fi kan Fani-Kayọde

Norrison ní "ìyàwó oníbàárà òun ló pe òun lórí ẹ̀rọ ìbánisọ̀rọ̀ pé ìléèwòsàn ti gba ọkọ òun nítẹ̀ẹ́.

Ṣàájú ni wọ́n ti fi ẹ̀sùn lílu owó tó n lọ sí bi i mílíọ́nù máàrùn Naira, tó jẹ́ owó ìlú ní pónpó kàn án àti àwọn méjì mì í.

Nenadi Usman nàá darapọ̀ mọ́ wọn

Mínísítà fún ètò ìnáwó nígbàkan rí, Abílékọ Nenadi Usman, tí wọ́n jọ fi ẹ̀sùn kan òun àti Fẹmi Fani-Kayọde, lọ̀jọ́ karùn ún, oṣù Kejìlá, 2017 nàá bẹ ilé ẹjọ́ gíga tìjọba àpapọ̀ tó wà ní ìlú Èkó láti fún un láàyè kó lọ sí ilẹ̀ Amẹrika fún ètò ìlera rẹ̀.

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Nenadi Usman ni mínísítà fún ètò ìnáwó Nàìjíríà láàrin 2006 sí 2007

Sáàjú ló ti sọ fún ilé ẹjọ́ pé àìsàn jẹjẹrẹ n bá òun fínra. Il''e ẹjọ́ gba ẹ̀bẹ̀ rẹ̀.

Ẹ̀sùn mẹ́tàdìnlógún ni àjọ EFCC fi kàn án, àti Fani-Kayọde, tó fi mọ́ alága nígbàkan rí fún ẹgbẹ́ àwọn ìjọba ìbẹ́lẹ̀ ní Nàìjíríà, Ọ̀gbẹ́ni Yusuf Danjuma.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí: