Òkùnkùn biribiri bí ilé iṣẹ́ mọ̀nà-mọ́ná ṣe jóná

Iná jọ́ ìlé iṣẹ́ mọ̀nọ̀-mọ́ná ní Ìkoyí
Àkọlé àwòrán Ìṣẹ̀lẹ̀ iná n'ìlé iṣẹ́ mọ̀nà-mọ́ná s'ọ̀pọ̀ èèyàn sí òkùnkùn biribiri ni Ìkoyí ní ìlú Èkó

Ìròyìn tó ń tẹ̀wá lọ́wọ́ sọ pé ìjàmbá iná ti ṣẹlẹ̀ ní ilé iṣẹ́ mọ̀nà-mọ́ná t'ówà ní Ìkòyí ní ìlú Èkó.

Ìṣẹ̀lẹ̀ náà ló sì ti sọ àwọn olùbárà ilé iṣẹ́ ọ̀un sí òkùnkùn biribiri.

Gẹ́gẹ́ bí a ti gbọ́, ìjàmbá iná yìí ṣẹ̀lẹ̀ ní bíi agogo mẹ́ta sí aago mẹ́wàá àárọ̀ Ọjọ́bọ tí í ṣe ọjọ́ kẹ̀ta oṣù karùn ún ọdún 2018.

Alukoro fún ilé iṣẹ́ panápaná ti ìlú Èkó, Ògbẹ́ni Shakiru Àmọ́dù, tó bá ilé iṣẹ́ iròyìn wa BBC Yorùbá sọ̀rọ̀ fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé ẹ̀rọ amúnáwá kan ni iná náà jó, kò sì ràn mọ́ ara ilé rárá.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionIná jò ilé iṣẹ́ mọ̀nọ̀-mọ́ná ní Ìkòyí ní ìlú Èkó

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí: