Rio Ferdinand kò rí ìwé àṣẹ fún ẹ̀ṣẹ́ kíkàn gbà

Agbábọ́ọ̀lù tẹ́lẹ̀rí Rio Ferdinand Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Ferdinand fi ìgbàkan rí jẹ́ ad'ẹ̀yìnmú fún ikọ̀ Manchester United

Agbábọ́ọ̀lù tẹ́lẹ̀rí fún ikọ̀ Manchester United, Rio Ferdinand, ni ó ti kùnnà láti rí ìwé àṣẹ fún ẹ̀ṣẹ́ kíkàn gbà

Ferdinand tí ó ti fìgbàkan rí jẹ́ ad'ẹ̀yìnmú fún ikọ̀ Man U, ló bẹ̀rẹ̀ ìgbáradì fún iṣẹ́ ẹ̀ṣẹ́ kíkàn ní oṣù kẹ̀sán an ọdún 2017.

Agbábọ́ọ̀lù náà tí ó jẹ́ ọmọ ọdún méjìdínlógójì fẹ̀yìn tì nínú eré bọ́ọ̀lù ní ọdún 2015.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Lẹ́yìn ìgbà náà ni ó sì ti mú ẹ̀ṣẹ́ kíkàn níbàádà.

Ṣùgbọ́n Ferdinand kò dun nún sí bí àwọn àjọ tó ń rì sí ẹ̀ṣẹ́ kíkàn n'ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì ṣe kọ̀ láti fún ní ìwé náà àṣẹ fún ẹ̀ṣẹ́ kíkàn.

Related Topics