Ìjẹ́jọ́ Dino; Femi Falana ní ó kù díẹ̀ káàtó fáwọn ọ́lọ̀páá

Dino Mélayé Image copyright Salleh Ashaka
Àkọlé àwòrán Ilé ẹjọ́ Kogi fi Dino Melaye sí àhàmọ́ tí'tí dí ọjọ́ ìgbẹ́jọ́

Ile Igbimọ Asojusofin, àjọ ajafẹtọ ọmọniyan lorilẹede Naijiria, àti amòfin àgbà, Femi Falana lo ti bu ẹnu atẹ lu bii ile-isẹ ọlọpaa lorilẹede Naijiria se fi panpẹ ọba mu sẹnetọ to n soju ẹkun idibo àárin gbungun Kogi, Dino Melaye lori idubulẹ aisan.

Falana ninu atẹjade kan sọ wipe ifiya jẹ ọmọ eniyan ati titẹ oju ofin to de ẹtọ ọmọ eniyan mọlẹ ni ohun ti awọn ọlọpaa se si ọgbẹni Dino Melaye.

Ajafẹtọ ọmọniyan naa ni iwe ofin ilẹ̀ Naijiria ko faaye gba ifiya jẹ ni, ati wipe oun ti Melaye n la kọja ni awọn mẹkunnu to ku n doju kọ lorilẹede Naijiria.

Falana wa ke si ile igbimọ asofin apaapọ lati sa ipa wọn ki ọrọ Dino Melaye o le yọri si rere.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Bakanna, ile igbimọ asofin ti kilọ fun awọn eleto aabo, paapa awọn ọlọpaa wipe nkankan ko gbọdọ se Dino Melaye lasiko to ba fi wa ni ahamọ wọn.

Lọjọ kẹta, Osu Karun ọdun 2018 ni ilé ẹjọ́ tó kalẹ̀ sì Lọkọja fi Sẹnetọ Dino Melaye sí àtìmọ́lé títí di ọjọ́ kọkánlá, Osú Kẹfa, ọdun kan naa.