BBC sọ̀rọ̀ lórí òfin tí Burundi fi dè é

Asia Burundi Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Burundi kò fẹ́ BBC fún ìgbà díẹ̀

Ilé iṣẹ́ BBC ṣe ìwádìí àṣẹ ti Ijọba Burundi pa pé kí wón dẹ́kun iṣẹ́ láti Ọjọ́ Keje oṣù Karùn ún ọdún 2018

Ìjọba orílẹ̀-èdè Burundi kéde òfin pé kí ilé iṣẹ́ BBC lọ rọọ́kún lati ọjọ́ Ajé to ń bọ̀ lataari pé ominú kọ wọ́n lórí ètò kan ti BBC ṣe sita.

Aláṣẹ ilé iṣẹ́ BBC ni, "Inú wa kò dùn sí ìpinnu ìjọba orílẹ̀-èdè Burundi, láti f'òfin de Ilé iṣẹ́ BBC bẹ̀rẹ̀ láti ọjọ́ Ajé tó m bọ̀.

"Ìjọba orílẹ̀-èdè Burundi ti kàn sí wa lórí ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò kan tí ilé iṣẹ́ BBC ṣe ni èdè Faranse lórí rédíò. Ati fi ara balẹ̀ yẹ ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò nínú ètò náà wò dáadáa, ní ìbámu pẹ̀lú kókó tó ń kọ wọn lóminu. A má a fún wọn ní èsì ní kíkún."

Ilé iṣẹ́ BBC ni, "A máa gbé ìgbesẹ̀ tó bá yẹ fún àtúnṣe tí ètò wa kankan kò bá kún ojú òṣùnwọ̀n gbèǹdéke ìlàna ètò bí ó ti tọ́ àti bí ó ti yẹ. "