Ọlọ́pàá: Ìwádìí ń lọ l'órí agbẹjọ́rò tí afurasí pé ó pa ọkọ

Otike Odibi ti iyawo re pa Image copyright Facebook
Àkọlé àwòrán Ọlọpaa ba oku Otike ninu agbara ẹjẹ l'ori ibusun.

Ile iṣe ọlọpaa ti Ipinle Eko ní awọn ti bẹrẹ iwadii l'ori agbẹjọro Udeme Odibi, ti wọn fẹ̀sùn kan pe o fi ọ̀bẹ pa ọkọ rẹ ni Diamond Estate, Sangotedo ni Ibeju Lekki ni òwúrọ̀ Ọjọbọ.

Oloogbe Otike Odibi ti o jẹ eni aadọta ọdun ni a gbọ pe wọn ba oku re ninu agbara ẹjẹ ninu ile wọn lẹ́yìn tí awọn aladugbo pe ọlọpaa pe wahala n sẹlẹ ninu ile naa.

Agbẹnusọ ile ise olopaa ni Ipinlẹ Eko Chike Oti ni nigba ti awọn agbofinro maa fi de ile naa, Udeme ti fẹ gbẹ̀mí ara rẹ̀, awọn aladugbo wọn si ti tètè gbe e lọ si ile iwosan.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionFídíò àkàndá ẹ̀dá tó di amòfin

Awọn aladugbo sọ pe agbẹjọro ni oloogbe naa bii ti iyawo rẹ ti ó jẹ́ ẹni ọdun métadinlaadọta. A gbọ pe ọdun mẹta sẹyin ni wọn di tọkọtaya.

Oti ni, "Bi agogo meje abọ owuro ni ọga ọlọpaa ti o wà ní Ogombo gbọ ipe pe iyawo oloogbe naa ti pa ni ile won ni Diamond Estate. Nigba ti awọn ọlọpaa si de ile naa, wọn ba oku oloogbe na ninu agbara ẹjẹ l'ori ibusun.

"Bi o ti lẹ jẹ pe ẹni afẹsunkan naa ṣi n gba itọju ni ile iwosan, Kọmiṣọna Ọlọpaa ni Ipinlẹ yii, Edgal Imohimi, ti paṣẹ fun awọn olùwádìí ẹka ẹsùn ipaniyan ki wọn lọ ile naa lati lọ kó awọn ẹri jọ."

Bákan naa ni BBC Yorùbá gbiyanju lati wọ ibi ti iṣẹlẹ naa ti ṣẹ ṣugbọn awọn ẹṣọ ti o wa ni ẹnu ọna Diamond Estate ko f'aaye gba awọn oniroyin lati wọle.

Wọn ni ọlọpaa nikan ni o ni agbara lati wọ adugbo naa lati wadi iṣẹlẹ naa.