Ọlọ́pàá gbé N5m silẹ̀ láti ṣàwárí àwọn adigunjalè Offa

Awọn afunrasi idigunjale Offa Image copyright NIGERIA POLICE
Àkọlé àwòrán Awọn afurasí náà gbẹ̀mi ogunlọ́gọ̀ ènìyàn pẹ̀lú ọlọ́pàá mẹsan

Ile ise lọ́pàá ti Ipinlé Kwara ti gbé miliọnu marun naira silẹ fun ẹnikẹni ti ó bá lé fun wọn ni ifitonileti l'ori awọn adigunjale ti ó kópa nínu ìkọlù si Offa ni Ọjo Kerin Oṣun Kẹrin ọdun yii.

Wọn si gbe aworan awọn afurasi naa l'akoko ìkọlu nibi ti wọn ti gbẹmi ogunlọgọ eniyan pelu ọlọpaa mẹsan eniyan jade pẹlu.

Agbẹnusọ fun ile iṣe ọlọpaa ni orile ede Naijiria, Moshood Jimoh, ti ó fi ọrọ naa to awọn oniroyin leti, sọ pe, yatọ si awọn afurasi ti ọwọ awọn ọlọpaa ti tẹ, wọn ti gbe orukọ awọn to ku lọ iwaju INTERPOL ki wọn baa le tete ri wọn mu.

Awọn aworan awọn afurasi yooku ti ọlọpaa gbe jade ree:

Image copyright NIGERIA POLICE
Àkọlé àwòrán Ọwọ ti tẹ awọn afurasi kan, sugbọn wọn ṣi n wa awọn miran