NAPTIP tún mú afurasí tó n kó ómódébìnrin lọ ilẹ̀ òkèèrè

Àwòran pátákó ìjúwe ilé ìtura Image copyright NAPTIP/facebook
Àkọlé àwòrán Ilé ìtura Amazonia ní wọn kó àwọn ọmọ òhun pamọ́ si

Àjọ to ń rí sì fayawọ ọmọniyan lorile-ede Naijiria (NAPTIP) ti gba àwọn ọmọbìnrin mẹ́tàlá kan silẹ.Wọn tú àwọn ọmọbìnrin náà silẹ lásìkò tí wọn ṣèwádìí lọ sí ilé ìgbàfẹ́ kàn to ń jẹ Amazonia Guest House ni agbègbè Gwagwalada n'ilu Abuja.Bákan náà ni ọwọ sinkun àjọ NAPTIP tó ọkùnrin kan, Afeez Abdulsalam, tí wọn ti ń wà fún ẹ̀sùn kíko àwọn ọmọbìnrin lọ sí orile-ede Saudi Arabia, ni bí ti wọn ti ń lò wọn fún onírúurú ìṣe ìdọ̀tí.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionIlé ìtura Amazonia ní wọn kó àwọn ọmọ òhun pamọ́ si

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Adarí ẹ̀ka kan nínú àjọ NAPTIP, Ogbẹ́ni Josiah Emerole, salaye pe, o tí pẹ́ tí àwọn tí ń ṣọ́ agbègbè náà kí àwọn tó rí wọn gbà sílẹ̀

Image copyright NAPTIP/facebook
Àkọlé àwòrán Ilé ẹjọ ní o fún àjọ NAPTIP láṣẹ láti ti ilé ìtura náà pa

Àjọ NAPTIP gbé ìgbése ọ̀hún pẹlu atileyin àṣẹ ilé ẹjọ́ láti sabewo sì ilé ìgbàfẹ́ náà tí wọn sì ti tíì pa báyìí títí tí ìwádìí yóò fi parí.