Ọmọogun Nàìjírìà: À ó fọwọ́sowọ́pọ̀ pẹ̀lú ẹgbẹ́ obìnrin

Àwòran àwọn Àjọ ọmọoogun àti ẹgbẹ náà Image copyright Nigeria Army/Twitter
Àkọlé àwòrán Àjọ ọmọoogun orílẹ̀-èdè ṣe ìpàdé pọ̀ pẹ̀lú ẹgbẹ́ obìnrin

Àjọ ọmọoogun orílẹ̀-èdè Nàìjíríà ti kéde ìpinnu wọn láti fọwọ́si ibaṣepo pẹ̀lú ẹgbẹ́ obìnrin kan nílé Áfíríkà láti túbọ̀ mú igbelárugẹ bá ẹ̀tọ́ ọmọniyan.

Oga àgbà Àjọ ọmọoogun orile-ede Naijiria, Tukur Buratai, ló jẹjẹ òhún lásìkò to gba àwọn Àjọ náà lálejò n'ilu Abuja.Lásìkò to ń bá àwọn ọmọ ẹgbẹ́ ohun sọ̀rọ̀ níbi ìpàdé tí Abileko Doris Joseph ,ti ẹgbẹ́ African Women leadership organizations ṣáájú rẹ ni Buratai ti gbóríyìn fún àwọn ẹgbẹ́ obìnrin ọ̀hún fún títiraka láti ja fún ẹtọ àwọn ènìyàn l'àwùjọ.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ó rọ wọn láti ṣe atileyin fún àwọn Àjọ ọmọoogun nípa títú àṣírí ohun tí kò bá tọ láyìíká kóówá wọn.Nínú èsì rẹ adarí ẹgbẹ́ ohun Doris Joseph ṣàlàyé pé ìpinnu ẹgbẹ́ náà ni lati gbe awon adarí tuntun dìde fún àwùjọ.