Ékìtì: Obìnrin mẹ́jì, ọkùnrin mọ́kànlélọ́gbọ̀n ń du ipò kan

Awọn olukopa idibo abẹle Ekiti Image copyright TWITTER/APC
Àkọlé àwòrán Papa iṣere Oluyemi Kayode ni idibo naa ti n waye ni Ado Ekiti

Idibo abẹle ti ẹgbẹ́ oṣelu APC n lọ lọwọ ni Ado Ekiti ní ipinlẹ̀ Ekiti

Ọkunrin ọgbọn ati obinrin meta ti jade lati du ipò gomina Ekiti lábẹ́ aṣia ẹgbẹ́ oṣelu APC ti yoo waye ni ọjọ kẹrinla oṣu keje.

Papa iṣere Oluyemi Kayode ni idibo naa ti n waye.

Gomina Ipinle Ekiti, Ayodele Fayose, ni oun kò bá má ti gbà wọn laaye láti lo ibẹ̀ bi ko ba ṣe ẹ̀mí ìfaradà fún alatakò ninu oṣelu ti òun ni.

A gbo pe, awọn olukopa ninu idibo naa ju ẹgbẹrun meji lọ ati pe Gomina Ipinlẹ Nasarawa, Umaru Tanko Al-Makura, lo n ṣe agbatẹru rẹ.

Bẹẹ gẹgẹ ni awọn ọlọpaa yí gbogbo agbegbe naa ká lati pese aabo ni papa iṣere naa.

Image copyright Abdullahi Garba Birnin Kudu
Àkọlé àwòrán Awọn olopaa n ṣiṣẹ wón nibi eto idibo ni Ekiti

Oriṣiriṣi iroyin ni o ti n jade lati ibi idibo naa bayii.

Bi idibo naa ṣe n lọ lọwọ ni òjò ṣe bẹrẹ si ni rọ ti awọn olukopa si n bẹru pe ojo naa ko ni jẹ́ ki wọn pari idibo ọhun.

Image copyright Abdullahi Garba Birnin Kudu
Àkọlé àwòrán Opolopo omo egbe oselu APC kun ibi idibo

Bi òjò naa ṣe da ni idibo tun tẹ̀ s'iwaju.

Bakan naa ni ifẹnuko ẹgbẹ oṣelu naa ni awọn wọọdu, ijọba ibilẹ ati ipinlẹ ti a mọ si congress n waye bi idibo naa ṣe n lọ.