Buhari ní òun kò ní gbẹ́yìn, Kemi Adeosun gba káàdì APC

Image copyright TWITTER/Bashir Ahmad
Àkọlé àwòrán Ifẹnuko wọọdu ẹgbẹ òṣelu APC ṣe n lọ lọwọ kakakiri orilẹ ede Naijiria

Bí ifẹnuko wọọdu ẹgbẹ òṣelu APC ṣe n lọ lọwọ kakakiri orilẹ ede Naijiria ni a gbo pe Aarẹ Muhammadu Buhari naa lọ kopa ni ìlú rẹ̀ ní Daura ní Ipinlẹ Katsina.

Awọn tí wọn jọ k'ọ́wọ̀ọ́ rin lọ sí ibi idibo ifẹnuko naa ti ó wáyé ni ile iwe Bayajidda ti o wà ni Daura ni Gomina Ipinlẹ naa Aminu Masari.

Awọn oludije ipo ninu ẹgbẹ APC, awọn olukopa ati awọn oṣiṣẹ́ ajọ INEC wa ni gbogbo wọọdu kakakiri orilẹ ede Naijiria lati ri pe eto naa lọ b'o ṣe yẹ kó rí.

Ọjogbọn Yemi Osinbajo, ti o je igbakeji aarẹ, wọọdu rẹ ti ó wa ni Agungi ni Eti Osa lo ti lọ ko'pa l'Eko.

Image copyright TWITTER/LAOLU AKANDE
Àkọlé àwòrán Igbakeji Aarẹ Osinbajo lọ si wọọdu rẹ ti ó wa ni Agungi ni Eti Osa lo ti lọ ko'pa l'Eko.

Osinbajo rọ awọn ara ilu ti o wa nibẹ pe ẹgbẹ APC yoo ṣe daada o ati pe wọn yoo ri jẹ ninu èrè Naijiria.

Image copyright TWITTER/LAOLU AKANDE
Àkọlé àwòrán Osinbajo ba awọn ara ilu sọrọ ni wọọdu rẹ

Bi Gomina Ipinle Kaduna, Nasir El-Rufai ṣe de wọọdu rẹ re:

Image copyright TWITTER/EL-RUFAI
Àkọlé àwòrán IIII

Olori ile igbọ asofin agba Bukola Saraki ni inu oun dun lati gbo pe idibo naa lọ ni irọwọrọsẹ ni Ipinlẹ Kwara.

Bakan naa, minisita fun eto ọrọ aje, Kemi Adeosun ni oun ti wa di ọmọ ẹgbẹ APC ni kikun bayi. O gba kaadi ọmọ ẹgbẹ ni wọọdu rẹ ni Abeokuta ni oni.

Gomina Ipinle Eko Akinwunmi Ambode naa ko gbẹyin bi oun naa ṣe lọ wọọdu rẹ lati lọ dibo.

Image copyright TWITTER/@AKINWUNMIAMBODE
Àkọlé àwòrán Gomina Ipinle Eko Akinwunmi Ambode naa ko gbẹyin o