Yobo: Ikọ̀ Naijiria gbọ́dọ̀ gbajumọ́ ìdije àkọ́kọ́

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Yobo ni ti ikọ Naijiria ba ja'we olu b'ori ninu idije kini, ọkan wọn yoo balẹ̀ si ni."

Joseph Yobo ti o jẹ amule fun ikọ agbabọlu orilẹ ede Naijiria nigba kan ri ti rọ ikọ orilẹ ede yii si idije ife ẹyẹ agbaye ki wọn gba'jumọ bi wọn ṣe maa ja'we olu b'ori ninu idije akọkọ wọn pelu Argentina.

Oni ko yẹ ki wọn maa sọrọ aṣekagba lati iwoyi.

Yobo ni, "Wọn gbọdọ ja'we olu b'ori ninu idije kini, ki wọn wa mura fun idije keji, lẹyin naa, idije kẹta. Ọkọọkan ni a n yọ ẹse l'eku. Mi o ro pe o dara ki a ja ku'lẹ ninu idije kini. Ti ikọ Naijiria ba ja'we olu b'ori ninu idije kini, ọkan wọn yoo balẹ̀ si ni."