Ayàwòrán: ọpọlọ, sùúrù àti agbára ni mò ń lò fún iṣẹ́ mi

Ìgbàkigbà ni ìmísí má a ń wá sí ọkàn mi fún yíya àwòrán

Olọ́tọ̀ ní tòun ọ̀tọ̀, Olumide Orẹṣegun tó ń ya àwòrán ní, kété tí mo ba ti ní ìmísí fún iṣẹ́ àwórán kan, ni màá kọọ silẹ̀ tàbí ki ń tẹ̀ẹ́ si orí fóònù mi.

Maa pe àwọn ọmọ jọ foríkorí wá ǹkan ti mò n fẹ́ lò, ki ó tó di odindin.

Àkọlé àwòrán,

'Ẹni mọ iyì wúrà ni à ń ta awòrán fún'

O mẹnuba oriṣii àwòrán to wà, ti wọn kọ́ nile ìwé pé:

  • Àwọn kan Àṣamọ̀ - Abstract
  • Àwọn kan Afòyemọ̀ - Realism
  • Àwọn kan maa n duro lọ́kàn ẹni - Impressionism
  • Àwọn kan maa ń ṣafihan - Expressionism
  • Àwọn kan n sọ nipa ọjọ́ ọ̀la - futuristim
  • Àwọn kan pegedé nínú afòyemọ̀ - Hyper- realism

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Olumide bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú eyi tó n wa lati ókàn rẹ̀ ni yíyà kí ó tó di ọ̀gá àgbà lẹ́nu iṣẹ́ rẹ̀.

O ni òun fi làákàyè ṣagbekalẹ àwón ohun eelo irinṣẹ aworan yiya to wọn ni Naijiria.