Ajàfẹ́tọ: Awàkọ̀ mi sùn ẹ̀wọ̀n ọjọ́ márùń t'orí aṣẹ́wó

Awọn olowo naabi duro si ẹgbẹ ọkọ Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Asẹwo di olùpẹ́jọ́ ti wọn fi fa Darlington de agọ ọlọpaa to wa ni Utako, Abuja

Ajafẹtọ ọmọ ènìyàn, Bukky Shonibare, tió ń gbé Abuja ti ṣ'alaye iṣẹlẹ kayefi kan ti o gbe awakọ rẹ ti o n jẹ Darlington lọ ẹwọn ọjọ marun fun ẹṣẹ ti ko m'ọwọ ti ko m'ẹsẹ.

Shonibare ni, "Arabinrin aṣẹwo kan ni o pe awọn ọlọpaa pe awakọ mi jọ ọkunrin kan ti o ja oun l'ole ni bii aago meta oru ni ọjọ kerin oṣu keta.

O fẹ lọ gbe eniyan kan ni ile igbafẹ kan ni Abuja ni aṣẹwo naa ba tọ'ka sii pe o jọ ọkunrin kan ti oun fẹ lọ sun si ọdọ rẹ, sugbọn ti o ja oun l'ole ki wọn to de'le."

Ajafẹtọ naa ṣ'alaye fun BBC Yoruba lórí wahala ti oun ṣe ki o to di pe Darlington jade ni ahamọ ọlọpaa nigba ti ko si ẹri kankan pe o jẹbi.

Ni orile ede Naijiria, iṣe asẹwo lodi s'ofin. Sugbọn, ni ọjọ Abamẹta, ọjọ kọkanleọgbọn oṣu kerin, asẹwo di olùpẹ́jọ́ ti wọn fi fa Darlington de agọ ọlọpaa to wa ni Utako, Abuja. Lẹyin naa ni wọn lọ tii m'ọle ni agọ ọlọpaa to wa ni Lugbe.

A gbọ pe aṣẹwo naa sọ fun awọn ọlọpaa pe oun pade ẹni to ja oun l'ole naa nile igbafẹ kan ni Abuja, ti ìná si wọ̀ laarin wọn. Onibaara naa ni oun yoo san ẹgbẹrun mewa naira fun aṣẹwo naa, ni o ba wọ inu ọkọ arakunrin naa.

Sugbọn o sọ fun awọn ọlọpaa pe bi awọn ṣe de agbegbe fasiti Baze ti o wa ni Abuja ni oníbàárà naa duro l'ẹgbẹ ọna ti o si fa ọbẹ yọ ti o gba gbogbo nkan to wa lọwọ oun.

Arabinrin naa tilẹ sọ fun awọn ọlọpaa pe nigba ti onibaara naa n ja oun l'ole, oun gee jẹ. Sugbọn Shonibarẹ ni nigba ti wọn gbe Darlington de agọ ọlọpaa, wọn bọ aṣọ rẹ, wọn ko ri àpá eyin kankan.

Shonibarẹ ni, "Wọn fi awakọ mi si ahamọ, lẹyin naa ni awọn ọlọpaa lọ ile re lati lọ wo boya wọn maa ri ẹri kankan, tabi awọn oun ti asẹwo naa ni o gba lọwọ oun. Wọn ko ri nkankan."

Ajafẹtọ naa ni nitori pe awakọ oun ti lo ju ọjọ meji ni ahamọ, oun sọ fun awọn ọlọpaa naa pe ofin ko gbaa laaye ki wọn ṣi ti mọle. Sugbọn ọlọpaa kan ni ko gbẹnu dakẹ.

Lẹyin ti wọn fa ọrọ naa titi ti wọn ko ri ẹri kankan, ni wọn ba fi Darlington silẹ o lẹyin ọjọ marun ni ahamọ.

Shonibare ni eyi to ya oun lẹnu ju ni pe, awọn ọlọpaa naa ko sọ nkankan nipa pe aṣẹwo naa n ṣe iṣẹ to lodi s'ofin.

Image copyright TWITTER/BUKKY SHONIBARE
Àkọlé àwòrán Shonibarẹ ni nigba ti wọn gbe Darlington de agọ ọlọpaa, wọn bọ aṣọ rẹ, wọn ko ri àpá eyin kankan

O ni, "Lẹyin ti wọn fi awakọ mi silẹ ni ọga ọlọpaa kan ni agọ naa sọ pe oun ti ri arakunrin kan ti o ni irùgbọ̀n bii ti awakọ mi.

O ni ki n gbaa ni imoran ko o lọ ge irugbọn rẹ o, ki wọn ma baa ṣìí mu fún ẹsẹ ti ko mọ'di rẹ."

Ọrọ Darlington ya ọpọ awọn eniyan lẹnu l'ori Twitter, ti wọn si n ba dupẹ pe ori koo yọ.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí: