Kaduna: Ẹ̀mí tó sọ nú nínú àkọlù àwọn agbébọn pọ̀

Àjókù ilé Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Púpọ̀ nínú àwọn tó pàdánù ẹ̀mí wọn ni ìròyìn sọ pé, wọ́n jẹ́ ọmọ ẹgbẹ́ ọdẹ ìbílẹ̀ kan.

Kò dín ní èèyàn mọkànléláàdọ́ta tó j'Ọ́lọ́run nípè ní ìpìnlẹ̀ Kaduna, àwọn t'ọ́rọ̀ ṣojú wọn ló sọ bẹ́ẹ̀.

Èyí wáyé lásìkò tí àwọn agbébọn ya wọ abúlé kan, tí wọ́n sì dáná sun ọ̀pọ̀lọpọ̀ ilé.

Púpọ̀ nínú àwọn tó pàdánù ẹ̀mí wọn ni ìròyìn sọ pé, wọ́n jẹ́ ọmọ ẹgbẹ́ ọdẹ ìbílẹ̀ kan, èyí tí wọ́n dásílẹ̀ láti maa pèsè ààbò fún àwọn abúlé tó wà ní agbègbè nàá, lẹ́yìn ti onírúùrú ìkọlù ti wáyé níbẹ̀. Àwọn ìkọlù ọ̀hún ni wọ́n di ẹ̀bi rẹ̀ ru àwọn olè a-jí-máàlù

Ṣaajú àsìkò yìí, inú fu, àyà fu, l'àwọn olùgbé ní àwọn abúlé tó wà ní tòsí Birnin Gwari wà.

Èyí ló sì mú kí wọ́n dá ikọ̀ aláàbò nàá sílẹ̀, ṣùgbọ́n, ipá wọn kò ká àwọn géndé agbébọn tó yí abúlé Gwaska ká lọ́sàn ań ọjọ́ Àbámẹ́ta, tí wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí ní yìnbọn, tó fi mọ́ dídáná sun ilé.

Àwọn t'órí kóyọ nínú ìkọlù nàá ti n késí iléèṣẹ́ ológun láti pèsè àwọn ọmọ ogun tí yóò maa dáàbò bo àwọn tó n gbé lẹ́nu àálà ìpínlẹ̀ Kaduna àti Zamfara.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí: