Awọn ọmọ ilẹ̀ Tunisia ń dìbọ ìjọba ìbílẹ̀

Olórí ẹgbẹ́ mùsùlùmí Ennahdha ilè Tunisia, Rached Ghannouchi Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Àwọn ọmọ ilẹ Tunisia n dìbò ìbílẹ̀ lọwọ

Orilẹ-ede Tunisia n dibo abẹle fun igba akọkọ lati ọdun 2011 ti ikólu Aarabu ti sẹlẹ.

Àwọn oludibo to le ni miliọnu marun un ni wọn n kopa ninu eto idibo ti awọn oludije to le ni ẹgbẹrun lọna ogun ti n dije.

Ijoba ilẹ naa ti fun awọn ijọba ibilẹ lagbara sii lẹyin ti wọn fẹ kí wọn maa kopa gidi ninu eto oṣelu ilẹ naa.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Awọn obinrin ko bi ida mẹrindinlaadọta ninu ọgọrun un awọn oludibo nilẹ naa.

Eyi jẹ igbesẹ ijọba ilẹ Tunisia lati rii pe ko ṣegbe lẹyin awọn okunrin ju obinrin lọ.