Cardiff ti gbégbá orókè láti kópa ní Premier League

Àwọn ẹgbẹ́ agbáọ́ọ̀lù Cardiff ta òmìn pẹ̀lú ikọ̀ Reading
Àkọlé àwòrán Ikọ̀ Cardiff yege lati kopa ínú ìdíje Premier League

Ikọ agbabọọlu Cardiff ti gbegba oroke lati kopa ninu idije Premier League ni saa to n bọ.

Ẹgbẹ agbabọọlu naa yege lẹyin igbati ti wọn gba òmì pẹlu ikò Reading ninu ifẹsẹwọnsẹ Championship to waye lọjọ aiku.

Ikọ Cardiff nilo lati jawe olubori tẹlẹ ninu ifẹsẹwọnsẹ naa ki wọn to le yege.

Ṣugbọn wọn gbegba oroke bi ẹgbẹ agbabọọlu Fulham ti fi di rẹmi pẹlu ayo mẹta si ọkan nile Birmingham.

Òmì ti wọn ta naa tun jẹ ko seese fun Reading lati dije ni liigi Championship ni saa to n bọ.

Related Topics