Ìdùnún ṣubú l'ayọ̀ bí Man City ṣe gba ife Premier League

Awọn agbabọọlu Man City ń dunún lẹyìn tí wọn gba ife EPL Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Manchester City gba ife eye Premier League

Idunu subu l'ayọ bi ikọ Manchester City ti gba ife ẹyẹ Premier League lẹyin gba ti wọn ta ọmin pẹlu Huddersfield l'ọsan ọjọ Aiku.

Ikọ naa ti pegede ninu idije liigi naa lati ọjọ kẹẹdogun oṣu kẹrin.

Ṣugbọn wọ́n ni lati duro di ọjọ Aiku lati gba ife ẹyẹ naa.

Awọn ololufẹ ẹgbẹ agbabọọlu naa ya wọ ori papa lẹyin ti ifẹsẹwọn naa tan.

Akọnimọọgba Manchester City Pep Guadioala lo kọkọ gba amin ẹyẹ olùborí.

Balogun ikọ naa Vincent Kompany lo gba amin ẹyẹ kan in ti wọn si gbe ife naa le lọwọ.