Ètò ìdìbò abẹ́lé APC: Ipeníjà fun ẹgbẹ ṣáájú 2019

Ami idanimọ APC Image copyright @APCNigeria
Àkọlé àwòrán Aáwọ̀ abẹ́nú lóríṣiiríṣìí ló ń ṣẹlẹ̀ ninu ẹgbẹ APC lorilẹ-ede Naijiria

Opin ọse to kọja ní ègbé òsèlú APC ṣe ètò ìdìbò jakejado orílè-èdè Nàìjíríà.

Láwọn agbegbe kàn ètò náà ló ní pèlé kutu ṣugbọn iroyin awuyewuye ati idarudapọ to fi mọ ẹhonu lo gbalẹ láwọn ìpínlè kàn.

Èkìtì

Image copyright Abdullahi Garba Birnin Kudu
Àkọlé àwòrán Awọn tí o wa nibẹ sọ wipé awọn kan tilẹ̀ ti ji apoti ibo gbe o.

Nnkan ò sẹnu re nibi ìdìbò abẹ́le to waye nipinle Ekiti.

Ojo lo kókó sebi ẹni da oju ojo ètò ru.

Lẹyin igba ti ojo dá, ètò náà gba ọna mi yọ ti awọn kan ji apoti ibo gbé ti awọn agbofinro sì bẹrẹ síí yinbọn soke.

Gómìnà ipinle Nasarawa,Tanko Al Makura to je alaga eto ipade idibo si kéde siso adagba eto ìdìbò náà ró titi di ọjọ miran.

Ekiti nikan ko

Ifehonuhan lo tẹlé ibo abele APC ìpínlẹ̀ Rivers ti awọn alatilẹyin Senato Magnus Abe n so wí pé kí ẹgbẹ má ṣe gbà èsì ìbò náà wọle.

Ni Òndó, a gbó pé aiṣedede wáyé níbi idibo náà ti wọn sì sun ọjọ idibo ìpínlẹ̀ Oyo lati ojo abameta s'ojo Aiku lẹyin ti awọn janduku da ètò ru ni ile ẹgbẹ ti o wa ni Oke Ado.

Ipínlẹ̀ Imo ati Abia naa wa lara ìpínlẹ̀ ti eto o ti lo ni irọwọrọsẹ

Awọn eekan ẹgbẹ kàn ko kópa

Bí ìròyìn dàrú dapọ ba koni lominu eyi to je kayefi ni bi awọn eekan ẹgbẹ náà kan ṣe ko lati yoju síbi ìdìbò náà l'agbegbe won.

Lara awon gbajugbaja ti a gbó pé won kọ lati yoju ni Senato Rabiu Musa Kwankwaso ati igbakeji Gómìnà, Kano,Hafiz Abubakar.

Alatako mu ọrọ APC gb

Ni kete ti ìròyìn nípa ìdìbò abẹle bẹrẹ sí tan ka lori afefe ni ẹgbẹ òṣèlú PDP ti fi ọrọ ṣòwò lójú òpó Twitter lati benu àtẹ lu ẹgbẹ APC

Gomina Ayo Fayose ko gbeyin

APC se agbekale ìgbìmò igbẹjo kòtẹmílọrùn

Ninu atejade kan Akọ̀wé ìpolongo fún ẹgbẹ́ APC, Bọ́lájí Abdullahi ní ìṣẹlẹ náà je oun to fọwọ kan ni lẹmi sugbọn "awọn tí yanjú òun tó dà rukerudo silẹ"

O ni alaga eto idibo abẹle ti sọrọ ''òun to sí kan ni ki a tẹsíwájú láì jafara.Ọrọ pe ka so eto ro titi di igba tí kò dájú ko ṣẹlẹ rara."

Ọjọ aje ni ìgbìmònaa yoo bere sini gbo ejo ehonu to wo wa latara eto idbo abela naa.