Ìpínlẹ̀ Kaduna ṣọ̀fọ̀ àwọn tó kú ni Birning Gwari lọ́jọ́ Abamẹta

ile to jona Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Opọ̀ ẹ̀mí ti sọnù ni Birnin Gwari tó fẹ́ sọ ibẹ̀ di ahoro

Opọ̀lọpọ̀ ìgbà ni àwọn oníṣẹ́ ibi yii ti kọlu Birnin Gwari, ti wọn si ti ké gbàjarè sijọba, ki gbogbo ẹ tó di ńlá lọ́jọ́ Abamẹta tó kọja ti wọn pa ènìyàn to le ni aadọta

Àwọn ìkọlù ọ̀hún ni wọ́n di ẹ̀bi rẹ̀ ru àwọn olè a-jí-máàlù kò pẹ àwọn ara abule naa ko fi aaye gba wọn lati fi ibẹ̀ ṣe ibujoko.

Ààrẹ Mùhámádù Bùhárí fi buwọ́lù ìdásílẹ̀ ọ̀wọ́ iléeṣẹ́ ọmọogun tuntun àti àwọn iléeṣẹ́ ọlọ́pàá tuntun lágbègbè Birnin Gwari ní ìpínlẹ̀ Kaduna.

Wọn ti sin òkú àwọn tó doloogbe latari ikọlu to waye gbẹyin lọjọ Abameta to jẹ ọjọ buruku èṣù gbomi mú.

Ijọba ipinlẹ̀ Kaduna ni àwọn òṣìṣẹ́ elétò ààbò yóò máa dáàbò bo àwọn ènìyàn agbegbe yii

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí: