Ọmọogun ilẹ̀ ri ẹgbẹ̀rún kan ènìyàn gbà padà lọ́wọ́ B/Haram

Awon ibon, awon omo odgun ile Image copyright @nigeriaarmytwitter
Àkọlé àwòrán Lafiya Doole ti tún hùwà akọni, wọn dóòlà ẹ̀mí odindi ẹgbẹ̀rún kan ènìyàn

Ikọ̀ àwọn ọmọogun ilẹ̀ Nàìjíríà, Troops of 22 Brigade, ti wọn ń ṣiṣẹ́ àkànṣe Lafiya doole, ti gba ẹgbẹ̀rún kan ènìyàn sílẹ̀ lọ́wọ́ àwọn oníṣẹ́ ibi boko haram.

Wọn ṣe iṣẹ́ àkànṣe náà pẹ́lú àpapọ̀ àwọn ọmọ ogun Multinational Joint Task Force (MNJTF).

Wọn gbà wọ́n kúrò ní abúlé Malamkari, Amchaka, Walasa ati Goranijọba ibilẹ̀ Bama nipinle Borno

Awọn ọmọdé àti obìnrin ló pọ̀jù ninu àwọn èrò naa

Ọkan ninu àwọn ti àwọn ọmọogun ilẹ̀ Nàìjíríà gbà silẹ̀ láti abúlé Amchaka, Alhaji Gambo Gulumba, dúpẹ́ lọ́wọ́ àwọn ọmọogun ilẹ̀ MNJTF fún òminra ti gbogbo wón ri gbà

Bakan naa ni àwọn ọmọogun ilẹ̀ Nàìjíríà tẹpẹlẹ mọ ìlérí wọn làti mójútó aabo dukia ati ẹ̀mí àwọn ènìyàn Nàìjíríà

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Wọn n ṣe ìtọ̀jú tó yẹ fún àwọn ènìyàn náà nile ìwòsàn àwọn ọmọogun bayii.

Eyi ni ìgbà kẹta laarin oṣù mẹrin ti àwọn ọmọogun ilẹ̀ Nàìjíríà ni wọn ri àwọn ènìyàn gbà padà lọwọ boko haram.