Àbọ̀dé Libya: Èeyàn 218 padà dé sí ìlú Èkó

Awọn abọde kan n sọkalẹ ninu baalu Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Ó lé l'ẹ́gbẹ̀rún mẹ́jọ àwọn ọmọ orílẹ̀èdè Nàíjíríà tí wọ́n ti kó padà dé láti orílẹ̀èdè Libya

Okòólénígba ó dín méjì làwọn ọmọ Nàíjíríà tí wọ́n kó padà dé láti orílẹ̀èdè Libya ni ọjọ́ ìṣẹ́gun.

Agogo mẹrin ìdájí kú díẹ̀ ni bàálù tó kó wọn balẹ̀ sí pápákọ̀ òfúrufú ìlú Èkó.

Mẹ́rìndínláàdóta nínú àwọn àbọ̀dé Libya náà ló jẹ́ obìnrin, méjì jẹ́ ọmọdé, tí mẹ́sán sì jẹ́ ọmọ ìkókó.

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Òkìkí ìwà ìmúnilẹ́rú lórílẹ̀èdè Libya ti kárí ayé.

Alámójútó àjọ tó ń mójú tó ìṣẹ̀lẹ̀ àjálù lórílẹ̀èdè Nàìjíríà, NEMA lẹ́kùn ìwọ̀ oòrùn gúúsù Nàìjíríà, Alhaji Yakubu Suleiman ló tẹ́wọ́ gba àwọn àbọ̀dé Libya náà, tó sì gba wọ́n níyànjú láti di olùfọnrere wàhálà àti ewu tó wà nínú sísá gba ọ̀nà ẹ̀bùrú r'òkè òkun .

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Àwọn àbòdé láti orílẹ̀èdè Libya yìí ni yóò jẹ́ kó di ẹgbẹ̀rún mẹ́jọ àti mọ́kàndínláàádoje àwọn ọmọ orílẹ̀èdè Nàíjíríà, tí wọ́n ti kó padà dé láti orílẹ̀èdè Libya báyìí, láti ìgbà tí òkìkí ìwà ìmúnilẹ́rú lórílẹ̀èdè náà ti kárí ayé.