Wenger: Àìleè kópa ní ife ẹ̀yẹ àgbáyé ba Koscielny nínú jẹ́

Agbábọ́ọ̀lù ìkọ Arsenal, Laurent Koscielny Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Koscielny fi ẹsẹ̀ ṣèṣe lásìkò tí Arsenal àti Athletico Madrid ń bá arawọn wàákò.

Agbábọ́ọ̀lù ìkọ Arsenal, Laurent Koscielny kò ní leè fi ẹsẹ̀ rẹ̀ gbá bọ́ọ̀lù fún oṣù mẹ́fà gbáko.

Koscielny fi ẹsẹ̀ ṣèṣe níbí ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ ìpele tó kángun si àṣekágbá ìdíje UEFA lọ́jọ́bọ tó kọjá.

Olùkọ́ni ìkọ agbábọ́ọ̀lù Arsenal, Arsene Wenger ṣàlàyé pé, iṣẹ́ abẹ tí wọ́n ṣe sórí iṣan ẹ̀yìn ẹsẹ̀ ti igbákejì Balógun ikọ̀ Arsenal náà fi pa.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ní báyìí olùkọ́ni fún ìkọ agbábọ́ọ̀lù orílẹèdè France, Didier Deschamps, ti fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé Koscielny kò leè kópa níbi ìdíje ife ẹ̀yẹ àgbáyé tí yóò wáyé loṣù kẹfà.

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán "Ó di oṣù Kejìlá ọdún yìí kì ẹ tó leè ríi lórí pápá."

Gẹ́gẹ́bí Arsene Wenger ṣe sọ, ìròyìn yìí ba Koscielny nínú jẹ́ pupọ̀.

"Ó di oṣù Kejìlá ọdún yìí kì ẹ tó leè ríi lórí pápá."

Ìṣẹ́jú Kejìlá ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ náà ni Koscielny fi ẹsẹ̀ ṣèṣe lásìkò tí Arsenal àti Athletico Madrid ń bá arawọn wàákò.