Wenger: Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lú ti kàn sí mi fún iṣẹ́

Akọ́nimọ̀ọ́gbá Arsenal Arsene Wenger Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Bọ́nà kan ò dí, òmíràn ò ní là. Wenger ti fẹ́ ríṣẹ́ míràn

Akọnimọọgba Arsenal to n lọ, Arsene Wenger, ti sọpe ọpọlọpọ ẹgbẹ agbabọọlu ni wọn ti kan si oun lati jẹ akọnimóógba wọn.

Wenger to ti lo ọdun mejilelogun gẹgẹ olukọni pẹlu égbẹ agbagbọọlu Arsenal. O gba idije Premier League lẹẹmẹta, to si gba ife ẹyẹ FA meje.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ṣugbọn Wenger sọ pe, oun si n kọju mọ iṣẹ oun ni Arsenal, nibayii ti ko ju bi oṣẹ meji lọ mọ ti yoo fi lọ.

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Ó dì gbà o, Arsene Wenger dágbére fún ikọ Arsenal

Wenger ni, oun ko ti wo ọkánkan ninu awọn ikọ agbabọọlu naa, ti wọn kan si oun.

Akọnimọọgba naa ni, oun yoo ṣiṣẹ wọ igbati akoko oun ni Arsenal yoo fi tan. Lẹyin igba naa ni oun yoo sinmi diẹ, ki oun to gba iṣẹ miran.