Ìbò abẹ́nú PDP Èkìtì: 421 ni Ẹlẹ́ka fi borí alátakò rẹ̀

Òjọ̀gbọ́n Kọ́lápọ̀ Olúsọlá Image copyright Facebook/Kolapo Eleka
Àkọlé àwòrán Òjọ̀gbọ́n Kọ́lápọ̀ Olúsọlá Ẹlẹka gbégbá orókè ínú ìdìbò abẹ́lé PDP fún ipò gómìnà l'Ekiti

Ọjọgbọn Kọlapọ Olusọla Ẹlẹka ni yoo dije fun ipo gomina labẹ ẹgbẹ oṣelu PDP ni ipinlẹ Ekiti ninu idibo ti yoo waye ni ọjọ kẹrinla osu keje.

Ọjọgbọn Ẹlẹka jawe olubori ninu ibo abẹle fun ipo gomina to waye l'ọjọ iṣégun l'Ekiti pẹlu ibo ẹgbẹ́run kan ati igba din kan.

Alatako rẹ ọmọọba Adebayọ Adeyẹyẹ ri ibo ọta le lẹẹdẹgbẹrin o le mẹwa.

Ibo mọkanlelogun o le nirinwo ni ọjọgbọn Ẹlẹka fi fagba han alatako rẹ.