Benue: Ọwọ́ ọlọ́pàá tẹ àwọn afurasí olókoòwò nkan ìjagun

Ọta ìbn àti ìbọn Image copyright Nigerian Police
Àkọlé àwòrán Àwọ́n afurasí ló n ta ìbọn AK47, àtàwọn nkan olóró miì fàwọn jàndùkú, ajìjàgbara àti daran-daran ní Benue àti Taraba.

Ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá Nàìjíríà ti tẹ àwọn afurasí tó n fi kátà-kárà nkan ìjagun, tí òfin kò fàáyè gbà ṣiṣẹ́ ṣe ní ìpínlẹ̀ Benue àti Taraba.

Àwọn afurasí ọ̀hún ni wọ́n fi ẹ̀sùn kàn pé, wọ́n n ta ìbọn AK47, àtàwọn nkan olóró miì fún àwọn jàndùkú, ajìjàgbara, tó fi mọ́ àwọn daran-daran àti àwọn àgbẹ̀ tó jẹ́ ọ̀daràn, ní ìpínlẹ̀ Benue àti Taraba.

Wọ́n fi wọ́n hàn lólú iléèṣẹ́ ọlọ́pà tó wà ní ìlú Abuja lọ́jọ́ kẹjọ, oṣù Karùn ún, ọdún 2018.

Lára àwọn tọ́wọ́ bà nàá ni Morris Ashwe, Kabiru Idris, Miracle Emmanuel àti Husseini Safiyanu, tí gbogbo wọn jẹ́ olókoòwò nkan ìjagun.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionÀwọn obìnrin Ìkòròdú: Ọdún orò kò ni wá lára rara

Bákan nàá ni ọwọ́ tẹ Emmanuel Ushehemba Kwembe, Sekad Uver, Ordure Fada, Stephen Jirgba, Peter Lorham, Achir Gabriel, àti Lorhemen Akwambe. Ẹ̀sùn tí wọ́n fi kàn wọ́n ni ijínigbé àti olè jíjà.

Image copyright Nigerian Police
Àkọlé àwòrán Àwọn afurasí nàá ló n ta nkan ìjagun fún àwọn adàlúrú ní Benue

Lára àwọn nkan ìjagun tí wọ́n gbà lọ́wọ́ wọn ni òjìlérúgba dín méjì ìbọn AK47 máàrùn ún, àti òjìlérúgba dín méjì ọta ìbọn.

Alukoro fún iléeṣẹ́ ọlọ́pà, Jimoh Moshood sọ nínú àtẹ̀jáde kan pé ìwádìí ṣì n tẹ̀síwájú, kawọ́ le tẹ àwọn afurasí yóòkù tó ti sálọ.

Image copyright Nigerian Police
Àkọlé àwòrán Ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá fi dá àwọn olùgbé ìpínlẹ̀ Benue àti àwọn tó múlé tì wọn lójú pé òun yóò ri dájú pé àláàfíà tó ti n jọba fi ẹsẹ̀ múlẹ̀.

Ẹ̀wẹ̀, Moshood sọ wí pé,''gbogbo àwọn tọ́wọ́ tẹ̀ nàá ni wọn yóò gbé lọ sí ilé ẹjọ́ níkété tí ìwádìí bá parí.

Ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ti wá fi dá àwọn olùgbé ìpínlẹ̀ Benue àti àwọn tó múlé tìí lójú pé òun yóò ri dájú pé àláàfíà tó ti n jọba fi ẹsẹ̀ múlẹ̀.