Ebola - DR Congo kéde ìtànkálẹ̀ ní ìhà àríwá orílèèdè

Aworan osise ilera Image copyright AFP
Àkọlé àwòrán Ìtànkálẹ̀ ààrùn Ebola tó wáyé kẹyìn lọdun 2017 pá èèyàn mẹ́rin.

Ìtànkálẹ̀ ààrùn Ebola ti ṣẹlẹ ní iwọ oórún àríwá orílèèdè DR Congo.

Ile iṣẹ ìlera fìdí ìṣẹlẹ méjì múlẹ wọ́n sì sọ wí pé ènìyàn mẹ́tàdínlógún ti pàdánù ẹ̀mí wọn.

Ìṣẹ̀lẹ̀ náà tó wáyé nílu Bikoro tún ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn ọdún kàn tí Ebola pa ènìyàn mẹ́rin lórílẹ̀èdè náà.

L'ọ́dun 2014, ó lè ní ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀fà ènìyàn tí ó bá ààrùn náà lọ ní Guinea, Sierra Leone àti Liberia.

Eléyìí ní ìgbà kẹẹ̀sán tí ààrùn Ebola yóò ṣẹlẹ ní DR Congo.

Ọdún 1976 ni wọ́n kọ́kọ́ ṣe àwárí kòkòrò afàìsàn náà nígbà tí orúkọ orílèèdè náà shì n jẹ Zaire.

Orúkọ odo ti wọn ti ṣe àwárí rẹ ni wọn fi perí ààrùn náà.