Pàṣípàrọ̀ Yuan si Naira: Èròngbà aráàlú ṣe ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀

Aworan awọn alase ile ifowopamo Nigeria ati China Image copyright PBC
Àkọlé àwòrán Ọjọ tí pé tí awọn orílẹèdè méjèjì tí n peroja àdéhùn paṣi paarọ owo náà

Èrò ṣe ọtọtọ lórí ìgbésẹ orílè-èdè Nàìjíríà láti yan ọwọ yuan orílèèdè China fun idokowo láàrin àwọn méjèjì.

Ìgbésẹ náà tó wáyé lẹyìn ìgbà tí àwọn méjèjì tọwọ bo iwe adehun paṣi paarọ Yuan pẹlu Naira, ni a gbọ wí pé, yóò mú adinku ba lílò dola fún idokowo láàrin àwọn orílèèdè méjèjì.

Ọ̀nà láti mọ anfaani tabi alebu to wa ninu igbesẹ yii lo mu ka kan sawọn eeyan ti eto pasi-paarọ owo ilẹ wa si ti ilẹ okeere gberu.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Lero ti Ken Ukaoha, to jẹ ààrẹ ẹgbẹ oníṣòwò lorílèèdè Nàìjíríà (NANTS) sọ wí pé, ìgbésẹ náà bójú mu.

O ni ''Ọjọ ti pẹ ti a ti n jẹ aràn irú ìgbésẹ báyìí nítorí bí káràkátà ti ṣe pọ láàrin orílèèdè Nàìjíríà àti China''

''Ṣẹ mo wí pé nnkan ko gùn régé láàrin Amerika ati China, fún ìdí èyí, a gbọdọ lo anfààní yii lati mu itẹsiwaju ba eto orò ajé wá.''

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán China ni orílèèdè ti káràkátà re pọju lọ pẹlu Nàìjíríà

Bákan náà ni ọjọgbọn Uche Uwaleke, to je Olùdarí ẹka imọ nipa eto ifowopamọ ati eto ìṣúná ni yunifásítì Nassarawa ní, ìgbésẹ náà ''yóò mú irọrun ba paṣi paarọ Náírà l'oja àgbáyé.''

''Ko ní sí wàhálà piparo Naira sí dollar ṣáájú ka to lee rà ojà lati China. Yóò sì jẹ kí Naira ni òkun sí ''

Ìpalára ni igbesẹ́ naa fún awon ilé iṣẹ Nàìjíríà

Sugbọn ohun to kọju si ẹnikan, ẹyin lo kọ̀ si ẹlomiran bii ilu gangan. Tóun ti bi ìgbésẹ yii ti ṣe dun to létí, ero awọn onimọ kan tako igbesẹ́ naa. Gẹ́gẹ́ bi wọn ti wi, o ṣeese ko mú ìpalára bá àwọn ilé iṣẹ to n pese ọja ni lorílèèdè Nàìjíríà.

Ninu ọrọ rẹ Uche Uwaleke ni ''oṣuwọn káràkátà fi sọdọ China ju Naijiria lo.''

Ìyè ọja tí Naijiria n ta fún China kéré sí èyí tó n wa lati ọdọ wọn. Fun ìdí èyí, a gbọdọ fi ofin rinlẹ pe kí àwọn olokoowo lati China wà dá ileese silẹ ni Nàìjíríà

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Ọdún mẹta ni wọn yóò fí ṣe àdéhùn paṣi paarọ náà

Awọn orilẹede ti China ṣe pàṣípàrọ̀ pẹlú rẹ

  • Banki àpapọ Yúrópù ti ṣe pasiparo tó tó owo biliọnu mẹ́tàdínlógọta pẹlú China.
  • Ilé Gẹẹsi náà se irúfé àdéhùn bẹ tó tó bílíọ̀nù mọ́kànlélógún poun.
  • India ati Brazil náà kò gbẹyin nínú àdéhùn yí.
  • Malaysia ati orílè-èdè China sọ àdéhùn pasi paarọ owo wọn dọtun fun ọdun meta si lọdun 2015.