Ebola: Nàìjíríà ń ṣọ́ pápákọ̀ òfurufú tórí Ebola

Awon osise ajo ti o n ri si iwole wode n saywo fun arinrinajo lo Mecca ni papako ofurufu Murtala Mohammed ni Eko ni ojo kokandinlogun osu kesan odun 2014. Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Àjọ tí ó ń rí sí ìwọlé-wọ̀de ní àwọn kó tún ní gba Ebola láàye o.

Àjọ tí ó ń rí sí ìwọlé wọ̀de ní àwọn yóò bẹ̀rẹ̀ sí ní ṣa ipa ju ti ẹ̀hìn wá lọ láti ríi pe Ebola tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣẹ́ yọ ni DR Congo kò wọ 'nú orílẹ̀ èdè Naijiria.

Agbẹnusọ àjọ náà, Sunday James sọ fún BBC pé gbogbo ọmọ orílẹ̀èdè yìí ní láti sapá wọn kí àìsàn búburú náà ti àwọn eléto ilera DR Congo ni ó ti pa eniyan mẹ́tàdínlógún báyìí, kó má ri 'bi jòkó ni ilẹ̀ẹ wa.

Ó ní, "A ó ránṣẹ́ si gbogbo àwọn òṣìṣẹ́ àjọ wa tí o wà ní gbogbo pápákọ̀ òfurufú pe kí wọn fojú sita, kí wọn tún máa lo ẹ́rọ tàmómítà tí wọ́n fi ń wo bí ǹkan ṣe ngbóná sí láti ṣ'àyẹ̀wò fun àwọn èrò.

"Bí a bá rí ẹni kankan tí ó dà bíi pé ó ní àìsàn kankan, a ó fa ẹni náà lé àwọn òṣìṣẹ́ ìlera tó wà ní pápákọ̀ òfurufú lọ́wọ́ lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀."

Ẹ ó rántí wípé ní ọdún 2014 ni Ebola wọ orílẹ̀èdè Nàìjíríà láti ọwọ́ arákùnrin ọmọ Sierra Leone kan, Patrick Sawyer tí ó gbe àìsàn náà wá láti orílẹ̀èdè rẹ̀. Enìyàn mẹ́jọ ni àìsàn náà pa lákòókò náà.

Ní báyìí, ilú Bikoro ni orílẹ̀èdè DR Congo ni a gbọ́ pé àìsàn náà tún ti bẹ́ jáde.