NYSC: ìdí tí a fí gba Davido láàyè láti jade

Davido

Oríṣun àwòrán, Instagram/Davido official

Àkọlé àwòrán,

Davido ti di asoju fun ile-isẹ ẹrọ ibaraẹnisọrọ, Infinix

Ilé iṣẹ́ agùnbánirọ tí ìpínlẹ̀ Eko sàlàyé pé àwọn fún Davido láàyè láti kúrò ní àagọ agùnbánirọ nítorí pé ó gbààyé pé ààbo àti aláfíà ẹmi oun kò gbópọn tó.

Òkìkí kan nígboro lẹ́yìn tí Davido fí fotò síta pé oun bẹ̀rẹ̀ ètò agúnbánirọ lẹ́yìn ọdun mẹ́ta tó parei ẹkọ rẹ̀ ní fasiti.

Ilé[-iṣẹ́ agunbanirọ sàlàyé péọdun lati sìnrú ilú baba ẹni ṣe pàtàki àti pé ọdun kan gbáko ló wà fún lójúnààti mú ìrẹ́pọ̀ wà láàrín gbogbo ẹku orílẹ̀-èdè yìí.

Bótill jẹ́ pé Davido fí fotò bó ṣe ń ṣe ìforukọsíll ní àgọ agunbanirọ ní Abulé Ẹgbá nínú oṣu tó kọja síbẹ̀ kò dúro lati parí ètò náà bó ṣe tún fi fótò míràn síta pé òun ní òde orin ní ilẹ̀ Amẹríkà.

Èyí ló fa ìdí abájọ oo tí gbogbo àwọn ènìyàn ṣe ń bèrè lóri ẹ̀rọ àyélujara pé ọ̀nà wọ ní Davido gba kú ní àgọ́ agùnbánirọ̀

Lẹyin 'Assurance'; Davido ra ọkọ ofurufu kekere

Oríṣun àwòrán, Instagram/Davido official

Àkọlé àwòrán,

Davido ti di asoju fun ile-isẹ ẹrọ ibaraẹnisọrọ, Infinix

Olorin taka-sufe nnì,David Adeleke, ti gbogbo eniyan mọ si Davido, ti di ọdọmọde akọkọ lati orilẹede Naijiria ti yoo ra ọkọ baalu kekere fun ara rẹ.

Davido, to pe orukọ ara rẹ ni ‘peace of mind’, ti sọ lori itakun ibaraẹnisọrọ Twitter rẹ pe, oun ti ra ọkọ baalu lẹyin ọkọ̀ ‘assurance’, iyen ọkọ ayọkẹlẹ to ra fun ọrẹbinrin rẹ, Chioma.

Iroyin naa waye lẹyin wakati diẹ ti ọrẹbinrin rẹ, ti wọn tun mọ si ‘personal assurance‘, Chioma Avril Rowland, bu ọwọ lu iwe ibasepọ lori isẹ́ ìdáná rẹ, ti Davido si di asoju fun ile-isẹ ẹrọ ibaraẹnisọrọ, Infinix.

Wayii o, èrò ọmọ Naijiria kan ree ninu ọpọ eeyan to ti fesi si igbesẹ tuntun Davido naa.