Shiite: Bí Buhari kò bá tú ZakZaky silẹ̀, apa APC kò níí káa mọ́

Àwọn ọmọlẹ́yìn Zakzaky
Àkọlé àwòrán Ìgbà àkọ́kọ́ kọ́ nìyí tí àwọn ọmọ ẹgbẹ́ Shiite yóò fẹ̀hónú hàn fún ìtúsílẹ̀ olori wọn

Ẹgbẹ́ ẹlẹ́sìn Islamic Movement kan ni Nàìjíríà, Shiite, ti ṣe ìfẹ̀hónú han lọ sí ilé ọ̀kan ninu aṣíwájú ẹgbẹ́ òṣèlù All Progressives Congress, APC, Aṣíwájú Bola Tinubu, tó wà ní ìlú Èkó.

Ìfẹ̀hònú hàn nàá tó wáyé lọ́jọ́ kẹsàn án, oṣù Karùn ún, ni wọ́n ṣe, láti fi rawọ́ ẹ̀bẹ̀ sí Tinubu, kó le bá Ààrẹ Muhammadu Buhari sọ̀rọ̀, láti tú olórí wọn, Ibrahim Zakzaky, sílẹ̀.

Zakzaky ti wà láhàmọ́ àwọn ẹ̀ṣọ́ aláàbò ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́ DSS, láti ọdún 2015.

Àkọlé àwòrán Shiite ní ó yẹ kí Tinubu lee bá Buhari sọ̀rọ̀ nípa Zakzaky.

Wọ́n ní, níwọ̀n ìgbà tó jẹ́ pé Tinubu jẹ́ ọ̀kan gbòógì, lára àwọn tó dá ẹgbẹ́ òṣèlú APC tó gbé Buhari wọlé sí ipò ààrẹ sílẹ̀, ó yẹ kó le bá a sọ̀rọ̀ nípa Zakzaky.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Muftau Zakariyau, tó jẹ́ Olùdarí ẹgbẹ́ Shiite ní ẹkùn Gúúsù ìwọ̀ oorùn Nàìjíríà, sọ fún BBC Yorùba pé, ''àwọn wá láti sọ fún Tinubu pé Buhari tó gbé wọlé sípò ti gbàbọ̀dè fún Nàìjíríà".

Àkọlé àwòrán Apá APC le má ká ohun tó le tẹ̀yìn rẹ̀ yọ tí Buhari bá kọ̀ láti tú Zakzaky sílẹ̀.

Àti pé apá APC le máà ká ohun tó le tẹ̀yìn rẹ̀ yọ tí Buhari bá kọ̀ láti tú Zakzaky sílẹ̀."

Ó ní ''àwọn kò ní sinmi ìfẹ̀hónú hàn títí tí ọ̀gá àwọn yóò fi gba òmìnira."