Sàràkí: Ọ̀gá ọlọ́pàá Nàíjíríà kò yẹ láti dipò òsèlú mú

Ọ̀gá ọlọ́pàá lórílẹ̀èdè Nàìjíríà, Ibrahim Idris Image copyright @PoliceNG
Àkọlé àwòrán Àwọn aṣòfin bojú wo ọ̀rọ̀ náà gẹ́gẹ́ bíi ìwà àìlákàsí àti àfojúdi.

Ilé aṣòfin àgbà ti kéde ọ̀gá ọlọ́pàá lórílẹ̀èdè Nàìjíríà, Ibrahim Idris gẹ́gẹ́ bíi ọ̀tá ìjọba tiwa-n-tiwa ti kò sì yẹ láti di ipò ìṣèjọba mú yálà lórílẹ̀èdè Nàìjíríà tàbí lókè òkun.

Èyí ni ọ̀rọ̀ tí ààrẹ ilé aṣòfin àgbà fi kásẹ̀ ọ̀rọ̀ rẹ̀ nílẹ̀, níbi ìjòkó ilé lọ́jọ́ọ̀rú lẹ́yìn tí Ibrahim Idris tún kùnà láti farahàn níwájú ilé.Ìgbà kẹ́ta nìyí tí ọ̀ga olọ́pàá Idris yóò máa kọ etí ikún sí ìpè àwọn aṣòfin àgbà láti wá wí tẹnu rẹ̀ lórí àwọn ìhùwàsí olọ́pàá lórílẹ̀ede Nàíjíríà.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Sẹ́nétọ̀ Sàràkí ní, lẹ́yìn ìpàdé ìdákọ́ńkọ́ tí wọ́n ṣe, àwọn aṣòfin bojú wo ọ̀rọ̀ náà gẹ́gẹ́ bíi ìwà àìlákàsí àti àfojúdi.