BBC: Ìhùwàsí iléẹ̀kọ́ IMT àti ọlọpàá kò jẹ́ ìtẹ́wọ́gbá

Ebere Ekeopara
Àkọlé àwòrán Akọ̀ròyìn BBC, Ebere Ekeopara, ni wọ́n gbámú, tí wọn sì tì mọ́lé fún wákàtí mẹ́rin lọ́jọ́ Ajé

Iléesẹ́ BBC ti se àpèjúwe ìhùwàsí àwọn ọlọ́pàá àtàwọn òsìsẹ́ iléẹ̀kọ́ gbogbo-ǹse Poly ti Enugu, lẹ́kùn ìlà òòrùn gúúsù Nàíjíríà, tí wọn yájú sí akọ̀ròyìn wa, Ebere Ekeopara, ti BBC Ìgbò, tí wọn sì tìí mọ́lé, gẹ́gẹ́ bíi èyítí kò jẹ́ ìtẹ́wọ́gbà.

Ekeopara ló lọ se àkójọpọ̀ ìròyìn kan ní iléẹ̀kọ́ ìmọ̀ ẹ̀rọ̀ IMT ní Enugu lọ́jọ́ ajé, nígbàtí àwọn òsìsẹ́ kan ya bòó, tí wọn sì fàá lé ọlọ́pàá lọ́wọ́.

Agbẹnusọ fún BBC ní "Ìhùwàsí iléẹ̀kọ́ náà àti àwọn ọlọpàá kò lẹ́tọ̀ọ́ rárá, tí kò sì jẹ́ ìtẹ́wọ́gbá."

Àkọlé àwòrán Wọ́n ba ọkọ̀ Ebere jẹ́ lásìkò wàhálà náà

Ọpẹ́lọpẹ́ kọmísánà ọlọ́pàá ní ìpínlẹ̀ náà, Mohammed Danmallam, tó ní kí wọn tú Ekeopara sílẹ̀.

Nígbà tí BBC kàn sí ọ̀gá àgbà iléẹ̀kọ́ Poly náà, ó ní ó yẹ kí akọ̀ròyìn náà gba àsẹ lọ́wọ́ iléẹ̀kọ́ náà, kó tó lọ kó ìròyìn jọ nínú iléẹ̀kọ́ náà.

"Ó ń fọ̀rọ̀ wá àwọn èèyàn lẹ́nu wò láì gba àsẹ. Mo ti ní káwọn ọlọpàá wọ́gilé ẹjọ́ náà."