Adájọ́ fi amòfin tó pá ọkọ rẹ̀ satìmọ́lé títí yoo fi gbàmọ̀ràn

Otike Odibi ti iyawo re pa Image copyright Facebook
Àkọlé àwòrán Adájọ fi aya olóògbé Otike sátìmọ́lé lẹ́yìn tó gbádùn nilé ìwòsàn

Udeme Odibi yóò wà látìmọ́lé tìtì Adájọ́ Kikẹlọmọ Ayeye yóò fi gba ìmọ́ran tó yẹ fún ìdájọ́ rẹ̀.

Adajọ Kikẹlọmọ tile ẹjọ Abẹ́lé ni Yaba ni ipinlẹ Eko ti ni ki Udeme Odibi, ti wọn fẹ̀sùn kàn pé ó pa ọkọ rẹ̀ Otike Odibi l'ọjọ Bọ to kója ṣi wà látìmọ́lé ná.

O sọ èyi lọjọ Ru nigba ti wọn gbe ẹjọ agbejọrò abilekọ ti wọn tún ni o gé ǹkan ọmọkunrin ọkọ rẹ̀ lẹ́yìn tó pa á, wà si ilé ẹjọ́.

Ẹsùn ìpànìyàn ni wọn fi kan agbẹjọrò ọmọ ọdun mejidinlaadọta ọhún, ni eyi to ṣe lodi si ofin ilẹ yii.

Oluṣẹyẹ Bamijoko, to jẹ agbẹjọrò olùjẹ́jọ́, bẹbẹ pe ki wón ti olùjẹ́jọ́ òun si ọgba ẹwọn ikoyi dipo ti kirikiri pèlú igbagbọ pe àwón onisegun oyinbo yóò le yẹ Udeme wo bi o ti yẹ.

O ni àwón dokita tó ń tọju agbẹjọrọ naa wa ni agbegbe Ikoyi si Victoria Island ni Eko.

Adajọ Ayeye ni ki wọn maa gbe Udeme lọ si ọgba éwón Kirikiri nitori pe kò si aaye fún obìnrin ni ọgba ẹwọn ikoyi bayii, ṣugbọn, ó ni ki wọn fún olujẹjọ naa laaye lati maa ri ẹbí àti agbẹjọrọ rẹ̀ nidakóńkọ́.

Bakan naa ló ni ki wọn má tíì sin òkú Otike, gẹgẹ bi wọn ṣe pinnu lọjọ Bọ tẹlẹ, ṣugbọn ki wọn duro ki iwadii fi parí ki wọn to sin in.

Adajọ sún ìgbẹ́jọ́ naa siwaju di ọjọ kẹẹdọgbọn, oṣu kẹfa ọdun.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ọdún méta ni àwọn agbẹjọro mejeeji fi jọ gbé ni lọ́kọláya ti wọn kò si bímọ fún ara wọn ki Otike tó doloogbe nile wón ni Daimond Estate ni Ajah nipinẹ Eko.