PDP: Ọ̀tẹ̀ tó pa wọ́n pọ̀ náà ló ń tu wọ́n ka

Olagunsoye Oyinlola Image copyright @AbekeOlamide
Àkọlé àwòrán Mo sa ipá mi ni NIMC gẹ́gẹ́ bii ọmọ Nàìjíríà rere ṣùgbọ́n mo fẹ́ tẹ̀siwaju ninu ìran míràn

Omọba Olagunsoye Oyinlola ti kọ̀wé fi ipò rẹ̀ silẹ̀ gẹ́gẹ́ bii alaga àjọ NIMC to ń ṣè káàdì ìdánimọ̀ ni Nàìjíríà, tó sì tún kúrò nínú ẹgbẹ́ òsèlú APC

Oyinlọla kọwe ìfipòsílẹ̀ náà ránṣẹ́ sí Aarẹ Buhari lọjọ kẹsan an osù karùn-ún.

Ó ní "Aarẹ, mo dúpẹ́ pé mo ni oore ọ̀fẹ́ láti sin ilẹ̀ baba mi gẹ́gẹ́ bi ipò ti mo dìmú. Mo ṣiṣẹ́ bi mo ṣe ni agbára to láti ṣee, ṣùgbọ́n o di dandan fún mi láti fipò yìi sílẹ̀, ki n lè gbájúmọ́ iṣẹ́ òṣèlù ti mo fẹ́ tọrun bọ̀

bayii. Emi kò jẹ́ dalẹ̀ ọga mi lẹ́nu iṣẹ́, ṣùgbọn mo fẹ́ tọ ipa ti ọkàn mi fẹ́ lásìkò yii ninu òṣèlu. Idí niyii ti mo ṣe gbọ́dọ̀ fi ipò mi silẹ̀ ni NIMC. Inú mi dùn fún bi ẹ ṣe gbàmi laaye láti sin ilẹ baba mi. Ní bayii, àsìkò ti tó fún mi láti sin àwọn ènìyàn mi lọna miran".

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ọ̀tẹ̀ tó pa wọ́n pọ̀ náà ló ń tu wọ́n ka

Wàyí ò, ẹgbẹ́ òsèlú PDP, tó jẹ́ ẹgbẹ́ òsèlú alátakò gbòógì ní ilẹ̀ Nàíjíríà, ti fèsì lórí ìsẹ̀lẹ̀ yìí.

Ọ̀gbẹ́ni Diran Odẹyẹmi, to jẹ́ oluranlọwọ alukoro ẹgbẹ́ òṣèlú PDP sàlàyé pé, ìgbésẹ́ Oyinlola yìí kò ya ẹgbẹ òṣèlú PDP lẹ́nu nitori pe kìí se ara wọn tẹ́lẹ̀-tẹ́lẹ̀.

Ó fi kún pé ọ̀tẹ̀ tó pa wọ́n pọ̀ náà ló ń tu wọ́n ka.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionOyinlọla kọ̀wé fipò rẹ̀ sílẹ̀ ni NIMC

Odẹyẹmi sọ̀rọ̀ lori àìsí agbára òfin lòdì sí ki àwọn ènìyàn maa ṣe aṣẹ́wó òṣèlú lati égbẹ́ òṣèlú kan si ìkejì.

O yẹ ki wọn maa padanu ipò wọn ti wọn ba ti kuro lati inu ẹgbẹ òṣelu kan si omiran ni.