Idá-omi ya pa ènìyan 27 ní Kenya

Awọn oṣiṣẹ ti o n doola ẹmi gbe oku eniyan kan dani lati ibi isẹlẹ na Image copyright AFP/Getty Images
Àkọlé àwòrán Ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ dúkìá àti ẹ̀mí ló ti ṣ'òfò nínú ìṣẹ̀lẹ̀ náà

Kò dín ní ènìyàn mẹtadinlọgbọn tí ó ti kú báyìí ní Kenya bí ìdá-omi kan ṣe ya ní ìlú Solai, ní apá àríwá Nairobi.

Gomina ẹkùn Nakuru, Lee Kinyajui, ní, "Omi tó ya láti Patel Dam ti ba ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ dúkìá jẹ́ tí ó si ti f'ẹ̀mí púpọ̀ ṣ'òfò. A kò tilẹ̀ tíì mọ bí òfò náà ṣe burú tó baáyìí."

Ẹgbẹ́ alaanu Red Cross ní orilẹ̀ èdè Kenya ni bí eniyan mọ́kàndínlógójì ni àwọn ti dóòlà ẹ̀mí wọn báyìí ti wọn ti kó lọ sile ìwòsàn fún ìtójú.

Àwọn tí ó n ṣe ìrànlọ́wọ́ fún àwọn tí ó fara kááṣa ìṣẹ̀lẹ̀ náà ṣàlàyé pé ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ ènìyàn ni ó rì sínú ẹrọ̀fọ̀ tí wọ́n ṣì ń wá.

Image copyright AFP/Getty Images
Àkọlé àwòrán Wọ́n ṣì ń wá ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ ènìyàn tí ó rì sínú ẹrọ̀fọ̀

A gbọ́ pé ìró ńlá dún nígbà tí ìdá omi náà ya ni oru. Bí omi náà ṣe ya ni ó kó àwọn ogunlọ́gọ̀ ilé tí ó wà ní ìsàlẹ̀ odò lọ.

Bíi ẹgbẹ̀rún méjì ènìyàn ni ó ti di aláìnílelórí báyìí.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Àwọn onímọ̀ nipa ojú ọjọ́ ni àrọ̀ọ̀rọ̀dá òjò to ń rọ̀ ni gbogbo ìlà oòrùn Afrika ló jẹ́ ki Omi ya pa ni Kenya ni èyí to n fa ikú ọ̀pọ̀ ènìyàn púpọ̀.