Magu: N100bn gan lo yẹ ká fi kọ́ ilé náà, mo sọ́wó ná ni

Olú iléeṣẹ́ EFCC Image copyright @officialEFCC
Àkọlé àwòrán Magu fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé olú iléeṣẹ́ tuntun nàá kò le gba gbogbo àwọn òṣìṣẹ́ àjọ nàá tó wà ní ìlú Abuja.

Ẹnu kò tí i sìn lára àjọ EFCC lórí iye tó lò láti kọ́ olú iléeṣẹ́ tuntun fún àjọ nàá.

Ilé tuntun ọ̀hún, ni alága àjọ nàá, tó n gbógun ti ìwà ìbàjẹ́ àti ìjẹkújẹ l'órílẹ̀èdè Nàìjíríà, Ibrahim Magu ní '' ó yẹ kí àwọn ọmọ Nàìjíríà yin òun ni fún lílo bílíọ́nù mẹ́rìnlélógún Naira fi kọ́ ilé tó yẹ kí àwọn kọ́ pẹ̀lú ọgọ́rùn bílíọ́nù Naira.

Owó nàá pọ̀ kọjá bó ṣeyẹ láti fi kọ́ ìlé alájà mẹ́wàá

Ilé alájà mẹ́wàá ọ̀hún tó wà ní ìlú Abuja, ni ìrètí wà pé Ààrẹ Muhammadu Buhari yóò ṣí lọ́jọ́ kẹẹ̀dógún, oṣù Karùn ún.

Àmọ́, Onímọ̀ kan nípa ìdíyelé ilẹ̀ àti ilé, tó bá BBC Yoruba sọ̀rọ̀ sọ pé "owó nàá pọ̀ kọjá bó ṣeyẹ láti fi kọ́ ìlé alájà mẹ́wàá nàá, tó fi mọ́ àwọn tó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ó ní, ó ṣeéṣe kí àwọn irinṣẹ́ ètò ààbò tó jẹ́ ojúlówó wà níbẹ̀, tó fi mọ́ àwọn nkan mìi tí wọ́n kó síbẹ̀, ṣùgbọ́n kò yẹ kí iye tí wọ́n nàá láti fi kọ́ ìlé nàá tó bẹ́ẹ̀."

Láìpẹ́ yii, ni àjọ EFCC ké gbàjarè pé àìsí owó tótó n ṣe ìdíwọ́ fún iṣẹ́ òhun. Ìbéèrè tó ti wá gba orí ẹ̀rọ ayélujára ni pé, ṣé àjọ tí kò rówó ṣiṣẹ́ yẹ kó ná mílíọ́nù mẹ́rìndínlógún láti fi kọ́lè.

Image copyright @officialEFCC
Àkọlé àwòrán Magu ni olú iléeṣẹ́ tuntun nàá kò le gba àwọn òṣìṣẹ́ tó wà ní ìlú Abuja.

Ìwé ìròyìn Premium Times jábọ̀ pé ''Magu fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé olú iléeṣẹ́ tuntun nàá kò le gba gbogbo àwọn òṣìṣẹ́ àjọ nàá tó wà ní ìlú Abuja. Àti pé, wọn yóò ṣi maa lo olú iléeṣẹ́ àtijọ́ tó wà ní agbègbè Adetokunbọ Ademọla, ní ìlú Abuja.

Bákan náà, ó ni, "àwọn òṣìṣẹ́ àjọ nàá tó fi àwọn ilé tí wọn yá ṣe ọ́fíìsì nílùú Abuja, yóò ṣì maa lo àwọn ilé nàá."