Iléẹjọ́: Ọjọ́ mérìnlá ló yẹ kí Omo-Agege fi jókòó sílé

Ovie Omo-Agege Image copyright @OvieOmoAgege
Àkọlé àwòrán Ileegbimọ aṣofin fi ẹsun kan an wipe oun lo dari awọn janduku to gbe ọpa asẹ ile lọ.

Ilé ẹjọ́ gíga ìjọba àpapọ̀ tó wà ní ìlú Abuj,a ti wọ́gi lé àṣẹ lọ gbélé rẹ, tí ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin àgbà pa fún Aṣòfin Ovie Omo-Agege.

Onídàjọ́ Nnamdi Dimgba, tó gbé ìdájọ́ nàá kalẹ̀ l'Ọ́jọ́bọ̀ sọ pé, ìgbésẹ̀ àwọn aṣòfin nàá kò bá òfin mu.

Ìwé ìròyìn The Punch jábọ̀ pé, Onídàjọ́ Dimgba ní ''bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ìlé aṣòfin ní agbára láti bá ọmọ ilé tó bá ṣìwà hù wí, ó ní, ọ̀nà tí wọ́n gbé ọ̀rọ̀ Omo-Agege gbà lòdì s'ófin, tó sì tún jẹ́ ìwà àrínfín sí ilé ẹjọ́.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Iléẹjọ́ fi kun pé àkọsílẹ̀ ìgbìmọ̀ ilé aṣòfin tó wà fún ìhùwàsí, tó gba àwọn aṣòfin nímọ̀ràn láti lé Omo-Agege lọ sílé, jẹ́ kó di mímọ̀ pé, wọ́n bá a wí nítorí pé ó pe ẹ̀jọ́ tako ilé aṣòfin lẹ́yìn tó tọrọ àforíjì lọ́wọ́ ilé fún ẹ̀sùn tí wọ́n fi kàn án.

Adájọ́ ní ilé ṣègbè pé ó gba Dino Melaye láàyè láti kópa níbi ìjókòó ilé

Ó fi kun pé, kò yẹ kí wọ́n da a dúró ju ọjọ́ mẹ́rìnlá lọ gẹ́gẹ́ bí òfin ilé ṣe là á kalẹ̀, '''ká ti ẹ̀ ní wọ́n gbe e gba ọ̀nà tó tọ́."

Ẹ̀wẹ̀, nínú ìdájọ́ náà, adájọ́ ní ilé ṣègbè fún bí ó ṣe fàáyè gba Aṣòfin Dino Melaye, tó pe ẹjọ́ tako Omo-Agege láti ma kópa níbi ìjókòó ilé.

Dimgba ti wá pa á láṣẹ pé, kí wọ́n gba Omo-Agege padà sílé lọ́gán, kí wọ́n sì san gbogbo àjẹmọ́nú, tó fi mọ́ owó oṣù tó tọ́ si lásìkò tó fi lọ rọ́ọ̀kún nílé.

Image copyright @NigeriaSenate
Àkọlé àwòrán Adájọ́ ní kí wọ́n sì san gbogbo àjẹmọ́nú, tó fi mọ́ owó oṣù tó tọ́ si lásìkò tó fi lọ rọ́ọ̀kún nílé.

Lọ́jọ́ kẹtàlá, oṣù Kẹrin ni ilé aṣòfin ní kó lọ rọ́ọ̀kún nílé fún àádọ́rùn ún ọjọ́ nítorí ọ̀rọ̀ tó sọ lórí àtúnṣe sí òfin ètò ìdìbò ọdún 2010, èyí tí wọ́n fi n pè fún àtuntò ìbò gbogbo-gbòò, pé Ààrẹ Muhammadu Buhari ni ìgbésẹ̀ nàá dojú kọ.

Ọjọ́ kejìdínlógún, oṣù Kẹrin nínú àtẹ̀jáde kan lórí ìsẹ̀lẹ̀ jíjí ọ̀pá àṣẹ ilé gbé, ni ilé asòfin àgbà fi ẹ̀sùn kan Ovie Omo-Agege pé òun ló kó àwọn jàndùkú sòdí láti gbé ọ̀pá àṣẹ nàá.