Oyinlọlá: A di ẹgbẹ́ òsèlú láti já ìjọba gbà lọ́wọ́ APC

Olóyè Olúsẹ́gun Ọbásanjọ́ àti èèyàn méjì míì
Àkọlé àwòrán Ọ̀nà láti jẹ́ kí àlá nípa ìdásílẹ̀ orílẹ̀èdè Nàíjíríà tuntun jọ, ló mú ká dara pọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ òsèlú ADC.

Asaájú ẹgbẹ́ alájùmọ̀se tí Olóyè Olúsẹ́gun Ọbásanjọ́ dá silẹ̀, Ọmọọba Ọlọ́gúnsóyè Oyinlọlá kéde pé, ẹgbẹ́ náà ti dara pọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ òsèlú African Democratic Congress ( ADC).

Oyinlọlá, níbi ìpàdé àwọn akọ̀ròyìn tó se ní àárọ̀ ọjọ́bọ, o ní, òun ti kọ́wé fi ẹgbẹ́ òsèlú APC sílẹ̀, láti bọ́ sí ADC, lọ́nà àti pa ègún àìní asaájú rere jẹ́ nílẹ̀ Nàíjíríà ni.

Àkọlé àwòrán Ẹgbẹ́ alájùmọ̀se gbé ìgbésẹ̀ náà láti se ara àwọn ní òsùsù ọwọ̀, fi já ìjọba gbà lọ́wọ́ ẹgbẹ́ òsèlú APC, nínú ìbò ọdún 2017.

Ó fi kun pé àwọn gbé ìgbésẹ̀ náà láti se ara àwọn ní òsùsù ọwọ̀, fi já ìjọba gbà lọ́wọ́ ẹgbẹ́ òsèlú APC, nínú ìbò ọdún 2017.

"Láti ìgbà tí a ti dá ẹgbẹ́ alájùmọ̀se sílẹ̀, làwọn ẹlẹ́gbẹ́-jẹgbẹ́ òsèlú ti ń kàn sí wa pé ka jọ fọwọ́-sowọ́pọ̀ di ọ̀kan. Àmọ́ lẹ́yìn ìjíròrò tó kún, làwọn adarí ẹgbẹ́ alájùmọ̀se wá pinnu láti dara pọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ òsèlú ADC."

Nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀ níbi ìpàdé akọ̀ròyìn náà, Olóyè Olúsẹ́gun Ọbásanjọ́ ní ọ̀nà láti jẹ́ kí àlá nípa ìdásílẹ̀ orílẹ̀èdè Nàíjíríà tuntun jọ, ló mú kí ẹgbẹ́ alájùmọ̀se náà dara pọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ òsèlú ADC.