OSIEC: A kò fi epo b‘ọyọ̀ lórí ìbò káńsù l'Ọ́yọ́

Awọn oludibo duro nibudo idibo kan Image copyright Oyo state government
Àkọlé àwòrán Eto idibo si ijọba ibilẹ yoo waye ni ipinlẹ Ọyọ ni ọjọ Satide

Eto idibo si ijọba ibilẹ yoo waye ni ipinlẹ Ọyọ ni ọjọ Satide, ọjọ́ kejìlá, osù karùn-ún, sugbọn oniruuru ede aiyede lo ti n waye lori rẹ.

Amọ ṣa, ajọ eleto idibo ipinlẹ Ọyọ ti sọ wi pe ko si ohun ti yoo yẹ idibo naa.

Ẹni to jẹ alaga fun ajọ eleto idibo ipinlẹ Ọyọ, Ọgbẹni Jide Ajeigbe ṣalaye fun BBC Yoruba pe, "Gbogbo eto lo ti to ati pe ilana ati igbesẹ gbogbo to yẹ ni gbigbe la ti gbe, lati rii pe awọn igun gbogbo ti ọrọ idibo naa kan fi ẹdọ lori oronro lori ato idibo naa.

Image copyright oyo state government
Àkọlé àwòrán Eyi ni igba akọkọ ti eto idibo si ijọba ibilẹ yoo maa waye ni ipinlẹ Ọyọ laarin ọdun mẹjọ

Ọgbẹni Ajeigbe ni, ẹru iwa idibajẹ atẹyinwa lo n ba awọn eeyan to n fapa janu lori eto idibo naa.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

O ni ko si idi fun awọn oloṣelu tabi oludibo lati ko aya soke lori iddibo naa nitoripe didun lọsan yoo so lori rẹ.

"Ibẹru iwa idibajẹ atẹyinwa lo faa ti awọn kan fi n kun. Bi ẹ ba woo, o ti to ọdun mẹjọ ti a ti dibo gbẹyin ni ipinlẹ Ọyọ; boya ẹru bi wọn ṣe maa n ṣe tẹlẹ lo n ba awọn eeyan naa. Ko si ẹni to lee tọka aleebu kan si eto idibo ti a fẹ ṣe yii o."

Awọn kan n kun lori idibo naa

Amọ o, bi eto idibo naa ṣe fẹ waye, adiyẹ ti ba lokun laarin ẹgbẹ oṣelu APC to n ṣejọba nipinlẹ Ọ̀yọ́, pẹlu bi awọn igun kan lagbo oṣelu naa se gba ile ẹjọ lọ lati ka ẹgbẹ oṣelu naa lọwọ ko ninu titẹsiwaju pẹlu lílo orukọ awọn to fi ṣọwọ gẹgẹ bii oludije labẹ aṣia ẹgbẹ oṣelu naa.

Ọmọwe Wasiu Ọlatunbọsun, to jẹ Ọkan lara awọn igun to n fẹhonu han ni, bi awọn agba ẹgbẹ kan pẹlu gomina Abiola Ajimọbi ṣe parapọ maa fi tipa gbe awọn oludije kan le awọn ọmọ ẹgbẹ lori, lo faa ti awọn fi n pariwo sita.

Ajimọbi àtàwọn ni wọn kọ orúkọ olùdíje fún APC

"Wọn ko tẹle ofin ẹgbẹ. Ohun ti ofin ẹgbẹ sọ ni pe, ẹni ti yoo dije fun ipo labẹ aṣia ẹgbẹ oṣelu gbọdọ jẹ awọn ti ọmọ ẹgbẹ mu funra wọn. Awọn ti ẹgbẹ fa kalẹ fun idibo yii, gomina atawọn eeyan kan ni wọn joko sile igbafẹ lati mu wọn."

O ni, awọn ti gba ileẹjọ lọ lori ọrọ naa ti ileẹjọ si ti kọkọ da wọn lọwọ kọ, ki o to tun di pe wọn ni ki wọn tẹ siwaju ṣugbọn igbẹjọ yoo maa lọ. Bi ile ẹjọ ba wa rii pe ilana to dari si idibo naa ko ba ofin mu, gbogbo rẹ ni wọn yoo da nu tiketike.

Idaniloju ajọ OSIEC lori idibo ọhun

Alaga ajọ eleto idibo ipinlẹ Ọyọ wa fi da awọn eeyan ipinlẹ naa loju pe didun lọsan yoo so lori eto naa.

Image copyright Oyo state government
Àkọlé àwòrán Awọn kan n fapa janu lori idibo naa

Bakanaa lo ni, ki eto naa lee so eso rere, ajọ ọhun ke si ajọ kan to n ri si ẹkọ nipa aṣeyori ibo lagbaye, International foundation for electoral System, IFES, fun idanilẹkọ ati igbani niyanju lori idibo naa.

"Awa o fi si igun kankan gẹgẹ bii ahesọ ọrọ ti awọn eeyan kan n sọ kaakiri. Gbogbo ilana ti a n ṣe la n ṣe ni gbangba."

Eyi ni igba akọkọ ti eto idibo si ijọba ibilẹ yoo maa waye ni ipinlẹ Ọyọ laarin ọdun mẹjọ.