Adéyẹyè: Òkùnkùn ni Fáyóṣé, ìmọ́lẹ̀ ni èmi

Adedayọ Adeyeye Image copyright @Adedayo_Adeyeye
Àkọlé àwòrán Adéyẹyè ni irọ lasan ni ohun ti awọn kan n sọ kiiri pe oun ti ṣe adehun pẹlu ẹgbẹ oṣelu APC

Adedayo Adeyeye, to ba igbakeji Fayose du asia oludije gomina lẹgbẹ oselu PDP l'Ékiti, ti fi ẹgbẹ oṣelu naa silẹ.

Adeyẹye kede igbesẹ lati fi ẹgbẹ oṣelu PDP silẹ, lẹyin to kuna ibo lati bori ibo abẹnu f'awọn oludije fun ipo gomina ninu ẹgbẹ naa.

Ọjọgbọn. Ẹlẹka ni ẹgbẹ PDP fa sita gẹgẹ bii oludije nibi eto idibo si ipo gomina ipinlẹ Ekiti, ti yoo waye ni ọjọ kẹrinla oṣu keje ọdun yii.

Bi o tilẹ jẹ pe, ko tii sọ ni pato ẹgbẹ oṣelu ti o n kọri si, amọ, Ọmọọba Adeyeye fi ẹsun kan Ayọdele Fayoṣe, to jẹ gomina ipinlẹ Ekiti lọwọ-lọwọ yii pe, ijọba fami-lete n tutọ lo n ṣe nipinlẹ naa ati laarin ẹgbẹ oṣelu PDP nibẹ.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ninu ọrọ to ba awọn akọroyin sọ nilu Ado Ekiti lọjọbọ, o ni, adehun wa laarin oun ati gomina fayose lori ọrọ oludije fun ẹgbẹ oṣelu naa, eleyi to ni gomina Fayoṣe ti tako bayii.

"Ko si ibarẹpọ to lee waye laarin okunkun ati imọlẹ,. Fayose duro fun okunkun ni eto oṣelu ipinlẹ Ekiti, eleyi ti ko see maa fẹnu sọ fawọn eeyan ipinlẹ yii.

Ko si bi mo ṣe lee maa tesiwaju pẹlu eeyan ti ko lee mu ileri ati adehun rẹ ṣẹ."

Image copyright facebook/Lere olayinka
Àkọlé àwòrán Adéyẹyè kò tíì sọ ẹgbẹ́ òṣèlú tí yóò darapọ̀ mọ́ láti díje fún ipò gómìnà ìpínlẹ̀ Èkìtì

Amọ sa, Adeyẹye ni ohun ko lọ si ẹgbẹ oṣelu APC bi awọn kan ṣe sọ.

O ni irọ lasan ni ohun ti awọn kan n sọ kiiri pe, ohun ti ṣe adehun pẹlu ẹgbẹ oṣelu APC lati di igbakeji oludije fun ipo gomina nibẹ.

" Kii ṣe ti igberaga, mo ti kọja ẹni ti yoo maa le igbakeji gomina kiri. Nitori awọn eto ti mo ni lati ṣe fun irapada ipinlẹ Ekiti ni."

Amọ sa, o ni ọyẹ yoo la lori ẹgbẹ oṣelu ti oun yoo darapọ mọ lati dije fun ipo gomina ipinlẹ naa laarin wakati diẹ laipẹ.