Ojú wo ni APC fẹ yàn fi kojú PDP l'Ekiti

Aworan ọmọ ẹgbẹ APC Image copyright Facebook/Ekiti APC
Àkọlé àwòrán Wọn kéde pé ìyípadà dé bá ibi ti ìdìbò náà yóò ti wáyé ni Ado Ekiti

Wákàtí diẹ loku ti ìdìbò abẹ́nú ẹgbẹ́ òṣèlú APC n'ipinle Èkìtì yóò fi wáyé.

Ọpọ èèyàn sí ti n woye ẹni tí yóò jáwé olúborí .

Olùdíje mẹ̀talèlọgbọ̀n ní o kọ́kọ́ kópa nínú ìdìbò náà lọ́sẹ̀ to kọja ṣùgbọ́n Babafemi Ojudu tó jẹ́ olùrànlọwọ fún Ààrẹ Buhari lórí ọrọ òṣèlú ni òun ko ní kópa mọ.

O ni òun fẹ dúró gẹ́gẹ́ bíi ''apẹ̀tù sááwọ̀ ni ipinlẹ̀ Ekiti.''

Àwọn wo ló kù bayi

Mínísítà fún alumọọni lorílè-èdè Nàìjíríà lọwọlọwọ, Kayode Fayemi wa nínú wọn.

O ti ṣe Gómìnà rí nipinle Ekiti ki Ayo Fayose to wa lórí aleefa bayii to gbà yọ kúrò.

Image copyright @kfayemi
Àkọlé àwòrán Kayode Fayemi yoo dupò pelu awon eniyan mẹẹdọgbọn si ipo

Ṣugbọn oun nìkan kọ ló ti ṣe gómìnà ríi tó tún n du ipò naa.

Segun Oni tó ṣe gómìnà láàrin ọdún 2007 sí 2010 náà n gbìyànjú ati ṣe lẹkan síí.

Ìdíje náà kò yọ àwọn míràn silè tọ fi mọ Senato Gbenga Àlùkò, Ogbeni Debo Àjàyí, Ọgbẹni Kayode Ọjọ ati Christanah Mojisola Kayode.

Ìpeníjà ìdìbò to yanranti

Image copyright Facebook/Taal Cirlce
Àkọlé àwòrán Ìpeníjà aabo to peye wa lara awọn nkan ti ẹgbẹ naa gbọdọ mojuto

Pẹlú bi dàrú-dapọ ti ṣe wáyé níbi ìbò abẹnu ti wọn kọkọ ṣe l'ose to kọjá, òpó tí n béèrè pé ṣé kò ní sí wàhálà leekeji.

Gómìnà Tanko Al Makura ti ìpínlè Nassarawa tí de si Èkìtì pẹlú àwọn ọmọ ìgbìmò eleto ìdìbò ẹgbẹ APC.

Lára àwọn àtúnṣe tí wọn kéde fún ìbò abẹ́nú ipinle Ekiti ni:

  • Lílò ibudo ibòmíràn fún ètò ìdìbò dipo pápá iṣere Oluyemi Kayode ti wọn lo l'ọse to kọjá,
  • Mímú ẹdinku bá ìyè èèyàn tí yóò wá ní ibudo ìdìbò
  • Pipese ààbò tó péye.

Bákan náà la gbó pé ìgbìmò náà yóò ṣe ọpọlọpọ ìpàdé pẹlu àwọn ọmọ ẹgbẹ ati awọn olùdíje láti ríi pé òun gbogbo lọ bi o ti yẹ.