Ọmọ Yahoo Plus: Wọn ní kí ń pa ìyá mi, kí ń lè lówó si ni

Taiwo gbe ọkan ninu igba ti wọn ba ninu ile rẹ lọwọ

Ileesẹ ọlọpaa ni Ipinlẹ Eko ti mu ọmọkunrin ẹni ọdun mọkandinlọgbọn kan ti orukọ rẹ njẹ Taiwo Akinola, ti o gbiyanju lati fi igi fọ ori iya rẹ ni adugbo Raji Ajanaku, ni Ayọbọ.

Ọjọ Aiku ni iṣẹlẹ naa ṣẹlẹ ninu ile ti Akinola n gbe pẹlu iya rẹ naa, Alice Akinola, ati ọmọdekunrin miiran kan.

Nigba ti awọn ọlọpaa mu Akinola, o jẹwọ wipe ọmọ ẹgbẹ okunkun Aiye ni oun.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Agbẹnusọ ọlọpaa ni Ipinlẹ Eko, Chike Oti ni, Akinola lọ sinu ṣọọbu ti iya rẹ naa ti n ta ọja niwaju ile wọn. O pee pe oun ni ọrọ pataki ti awọn dijọ fẹ jiroro ninu ile, asiko yii naa lo si ran ọmọ ẹgbọn rẹ kekere, Farouk, ti wọn jọ n gbe inu ile nisẹ, lati lọ ra asọ pelebe inuju (handkerchief) funfun, wa fun oun.

Bi iya Taiwo se wọle wa, lati da ọmọ rẹ lohun, ni Taiwo yii fi igi nla, ẹrọ ilọsọ (iron) ati ẹrọ to n tan ina si idi Kọmputa, (UPS) gbaa lori lọna ati ri daju pe iya rẹ ko ye isẹlẹ naa.

Amọ nigba ti Farouk to ran nisẹ de, lo ri iya wọn ninu agbara ẹjẹ, to si fi igbe ta pe kawọn ara adugbo wa gba iya oun. Awọn aladugbo to de sibẹ lo ransẹ pe awọn ọlọpaa to gbe iya Taiwo lọ sile iwosan, amọ ko tii yaju titi di akoko yii.

Nigba to n salaye fawọn ọlọpaa lori ohun to ri lọbẹ, to fi waru sọwọ, Taiwo ni wọn ni ki oun lọ pa iya oun ki oun lee ni owo sii ni.

Ọlọpaa ri awọn ohun ara meriri ni yara Taiwo

Lasiko tawọn ọlọpaa sayẹwo ile rẹ, wọn ba igba meji, ti ọkan ni ori oku ninu, nigba ti igba keji kun fun agbo dudu.

Bakan naa ni wọn ri igi kan ti wọn fi iso gun kaakiri eyi ti ẹjẹ wa lara rẹ, ẹrọ ilọsọ to ni ẹjẹ lara, asọ inuju funfun kan to fẹ fi nu ẹjẹ iya rẹ ati igo to kun fun ororo ti wọn kọ ‘back to sender’ si lara.

Ileesẹ ọlọpaa ti wa kesi awọn olugbe ipinlẹ Eko lati dide tako iwakiwa to nii se pẹlu iwa ọdaran nitori iwa gbigba kamu si ohun to lewu kọ ni ọna abayọ sawọn iwa ọdaran bii iru eyi.

Àkọlé àwòrán,

Ọrọ dii bo o lọ, oya a mi ni ile igbafẹ Club 57, ni Ikoyi, Lagos

Ninu iroyin miran ẹwẹ, ajọ to n gbogun ti iwa ibajẹ lorilẹede Naijiria, EFCC, sọ wi pe, oun ti fi panpẹ ọba mu awọn afurasi ọmọ yahoo yahoo mejila, ni ile igbafẹ Club 57 ni Ikoyi ni ipinlẹ Eko.

Ajọ EFCC ni, wọn gbe igbesẹ naa lowurọ kutu ọjọ Ẹtì, ọjọ́ kọkanla, Osu Karun, ọdun 2018, lẹyin ti awọn eeyan kan gbe si wọn leti pe, awọn afunrasi onijibiti naa n sọsẹ ni agbeegbe naa.

Ajọ naa, tó sisọ loju ọrọ naa loju opo Twitter rẹ fi kun pe, ọrọ dii bo o lọ, oya a mi, sugbọn awọn ri ọkọ ayọkẹlẹ mẹwa gba silẹ, ti awọn si fi panpẹ ọba mu awọn mejila miran ni bi ile igbafẹ naa.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Bakan naa lo ni awọn ọmọ 419 yii kan sa mọ awọn lọwọ, ti wọn si fi ọkọ ayọkẹlẹ, olowo iyebiye wọn silẹ, fẹsẹ fẹẹ.

Skip Twitter post, 1

End of Twitter post, 1