CAN: Ìbànújẹ́ ńlá ni iku ọ̀mọ̀wé Musa Asake jẹ

Ọmọwe Musa Asake Image copyright Dailypost
Àkọlé àwòrán Owurọ ọjọ ẹti ni akọwe ẹgbẹ CAN naa jade laye nilu Abuja lẹyin aisan ranpẹ

Akọwe ẹgbẹ ọmọlẹyin kristi ni orilẹede Naijiria, CAN, Ọmọwe Musa Asake, ni iroyin sọ wi pe o ti jade laye bayii.

Atẹjade kan, ti ẹgbẹ naa fi ṣọwọ si BBC Yoruba, tun fi kun pe oloogbe naa silẹ bora lẹyin aisan ranpẹ.

Iku oloogbe naa n waye ni nkan bii ọsẹ meji to lewaju iwọde jakejado orilẹede Naijiria, eyiti wọn fẹ fi dide tako bi awọn darandaran Fulani ṣe n pa awọn eeyan kaakiri.

Ni ọdun 1976, ni iranṣẹ Ọlọrun Musa Asake bẹrẹ iṣẹ iranṣẹ rẹ ni ijọ ECWA to wa ni ilu rẹ ni Unguwar Rimi, Bajju nijọba ibilẹ Zangon Kataf, nipinlẹ Kaduna.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionAborisade: Mẹ̀kúnù gbọ́dọ̀ funra sí Obasanjo

Iranṣẹ Ọlọrun naa kun ara awọn ohun to n fọn tan-tan-tan lori wahala ọrọ aabo lorilẹede Naijiria, paapaa julọ, ni idi didaabo bo awọn ọmọlẹyin Kristi.

Nibayii, Aarẹ Muhammadu Buhari ti ranṣẹ ibanikẹdun si awọn ọmọlẹyin Kristi lori iku iranṣẹ Ọlọrun naa.

Ninu atẹjade kan ti agbẹnusọ fun aarẹ, Fẹmi Adeṣina fi sita, Aarẹ Buhari gba a ladura pe, ki Ọlọrun tu awọn ẹbi rẹ ninu.