Ajimọbi: Ààbò wà nílẹ̀ láti kojú mọ̀dàrú lásìkò ìbò

Gomina Abiola Ajimọbi Image copyright oyo state government

Ijọba ipinlẹ Ọyọ ti ranṣẹ ikilọ sawọn eeyan tabi ẹlẹgbẹjẹgbẹ to lee fẹ da wahala silẹ lasiko idibo sijọba ibilẹ ti yoo waye nipinlẹ naa lọjọ abamẹta.

O ni Awọn agbofinro ti wa nikalẹ lati fi irufẹ awọn eeyan bẹẹ jofin.

Atẹjade kan ti oluranwọ fun gomina ipinlẹ Ọyọ lori ọrọ oṣelu, Ọmọwe Morounkọla Thomas fi sita ṣalaye pe, ikilọ yii ṣe pataki pẹlu iroyin ti o n jade pe, awọn ẹgbẹ onikọlọransi kan laarin ẹgbẹ oṣelu APC, n gbero lati da họwuhọwu silẹ lọjọ abamẹta.

Image copyright oyo state government
Àkọlé àwòrán Ijọ̀ba ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ ní ètò ti tò lórí ìpèsè ààbò lásìkò ìbò náà

Ijọba ipinlẹ ipinlẹ Ọyọ ni, gbogbo eto to yẹ fun idaabo bo ẹmi ati dukia ṣaaju, lasiko ati lẹyin idibo naa, ni wọn ti gbe kalẹ.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Gẹgẹ bii atẹjade naa ṣe sọ, iroyin kan ti tẹ ijọba lọwọ pe, awọn ọmọ ẹgbẹ kan ti wọn n pe ni Unity Forum, ti n gbero lati lo awọn janduku fi kọlu awọn oludibo lasiko idibo naa.

BBC Yoruba gbiyanju lati gbọ tẹnu ẹgbẹ Unity Forum lori ẹsun naa, ṣugbọn olotu ẹgbẹ naa, Ọmọwe Wasiu Ọlatunbọsun ko gbe ẹrọ ibanisọrọ rẹ, nigba ti a pee, ki a to ko iroyin yii jọ.