Buhari padà sí Naijiria lẹ́yìn tó lọ tọ́jú ara rẹ̀

Muhammadu Buhari Image copyright @BashirAhmaad
Àkọlé àwòrán Ni ọjọ iṣẹgun ni Aarẹ Buhari fi orilẹede Naijiria silẹ

Aarẹ Muhammadu ti pada si ilu Abuja, lẹyin to lọ si ilu ọba lati gba itọju lọdọ dokita rẹ.

Ni nkan bii agogo meje ku diẹ lalẹ ọjọ ẹti, ni baalu to gbe aarẹ gunlẹ si papakọ ofurufu Nnamdi Azikwe nilu Abuja.

Ni ọjọ iṣẹgun ni Aarẹ Buhari fi orilẹede Naijiria silẹ lọ si ilu Lọndọn, lẹnu irinajo ati tọju ara rẹ.