Akọ́nimọ̀ọ́gbá ikọ̀ DC United fẹ́ ra Rooney lọ sí MLS

Àgbàọ̀jẹ̀ agbábọ́ọ̀lù Wayne Rooney Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán ọ̀pọ̀ ikọ̀ agbábọ́ọ̀lù MLS ní orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà l'óbá aṣojú Rooney, Paul Stretford, sọ̀rọ̀ bíi ọdún kan sẹ́yìn

Akọọnimọgba ikọ DC United ń ṣẹ́jú sí Wayne Rooney, tó jẹ́ ọ̀kan lára agba-ọjẹ agbabọọlu àgbáyé

Ṣugbọn DC United fidi rẹ mulẹ pe ikọ naa ko tii ra Rooney lati ẹgbẹ agbabọọlu ilẹ Gẹẹsi, Everton ti ó ń ṣoju lọwọ.

Iroyin kan laarin ọṣẹ yii ni ifẹnuko ti wa lori bi Rooney yoo ṣe di ọmọ ẹgbẹ agbọọlu DC United fun owo tó tó £12m.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ọpọ ikọ agbabọọlu MLS ni orilẹ-ede Amẹrika loba aṣoju Rooney, Paul Stretford, sọrọ bii ọdun kan séyin, ki o to lọ darapọ mọ Everton lati Manchester United.

Rooney to jẹ ọmọ ọdun mejilelọgbọn ni agbabọọlu to gba bọọlu s'awọn julọ fun ilẹ Gẹẹsi.