NAFDAC gbẹ́sẹ̀ kúrò lórí òfin tó fi de àwọn iléeṣẹ́ apòògùn

Àwọn àwòrán ìgò oògùn ikọ́ olómi tó ní èròjà codeine
Àkọlé àwòrán Àṣìlò òògùn ikọ́ olómi tó ní èròjà codeine nínú máa ń fa ki kíndìrín bàjẹ́, gìri, ọpọlọ dídàrú àti orí yíyí.

Àjọ tó n mójútó ìpèsè oúnjẹ àti òògùn lílò ní Nàìjíríà, NAFDAC, ti gbẹ́sẹ̀ kúrò lórí òfin tó fi de àwọn ilé iṣẹ́ apòògùn kan látàrí ìwádìí BBC lórí codeine.

Ṣáàjú ni àjọ nàá tí gbé ilẹ̀kùn àwọn iléeṣẹ́ nàá, Peace Standard, Emzor àti Bioraj, táwọn méjéèjì wà ní ìpínlẹ̀ Èkó àti Kwara tì pa fún ipa tí wọ́n kó lórí ìtànkálẹ̀ ògùn ikọ́ olómi tó ní èròjà codeine nínú, èyí tí àwọn ọ̀dọ́ Nàìjíríà ti sọ di egbòogi, tí wọ́n n lò ní ìlòkulò.

Àkọlé àwòrán Iléeṣẹ́ Bioraj, Emzor àti Peace Standard ni ìwádìí fihàn pé wọn jẹ́bi bí òògùn codeine ṣe tàn kálẹ̀

Àbọ̀ ìwádìí àjọ NAFDAC, tó ṣe lẹ́yìn fídíò ìṣẹ́ ìwádìí BBC tú àṣírí ìlòkulò òògùn nàá, fihàn pé lóòtọ́ ni iléeṣẹ́ Bioraj jẹ́bi

  • Àì ṣàmójútó àwọn alágbàtà rẹ̀
  • Pé ọ̀nà tó n gbà kó àwọn òògùn rẹ̀ pamọ́ kò bójú mu
  • Ìlànà tó fi n pèsè àwọn òògùn rẹ̀ kò dára rárá
  • Àti pé òṣìṣẹ́ rẹ̀ kan lẹ̀dí àpò mọ́ ọ́kan tí wọ́n ti lé kúrò lẹ́nu iṣẹ́ láti maa ta èròjà codeine tí wọ́n jí kó ní iléeṣẹ́ nàá lọ́nà tí kò bófin mu.
  • Àì pèsè ààbò tó múná dókò, èyí tó fà á tí alágbàtà rẹ̀ tí ìwádìí BBC ṣe àfihàn ojú rẹ̀ fi ráyè sálọ.

Wọ́n ní iléeṣẹ́ Emzor nàá jẹ̀bi:

  • Ṣíṣe ìdíwọ́ tó fi mọ́ kíkó ẹ̀rí pamọ́ lásìkò tí ikọ̀ NAFDAC ṣe àbẹ̀wò sí ọgbà iléeṣẹ́ nàá.
  • Àì ní àkọsílẹ̀ tó pójú owó lórí òdinwọ̀n èròjà codeine tí wọ́n n lò.
  • Màgòmágó nínú àwọn ìwé àkọsílẹ̀ fún bí wọ́n ṣe n kó ọjà wọn láti ibìkan sí òmí.
  • Àti pé kò maa ṣe àmójútó àwọn alágbàtà tó ní òntẹ̀

Àjọ NAFDAC nínú àtẹ̀jáde kan tí olùdarí rẹ̀, Ọ̀jọ̀gbọ́n Mojisọla Christianah Adeyẹye, fi ọ̀wọ́ sí, ti ní kí àwọn iléeṣẹ́ apòògùn mẹ́tẹ̀ẹ́ta dáwọ́ ṣíṣe òògùn ikọ́ olómi tó ní èròjà codeine dúró lọ́gán, kí wọ́n ó sì gba gbogbo èyí tí wan ti tà síta padà fún àyẹ̀wò lọ́dọ̀ NAFDAC.

Image copyright Frankieleon
Àkọlé àwòrán Àṣìlò codeine wọ́pọ̀ láàrin àwọn ọ̀dọ́

Ẹ̀wẹ̀, wọ́n ní kò ní i sí ààyè láti kọ̀wé tuntun bèérè fún àṣẹ láti kó codeine wọ́lé láti ilẹ̀ òkèérè gẹ́gẹ́ bi èròjà gbòógì fún ṣíṣe òògùn ikọ́ olómi, tàbí sọ èyì tó ti wà nílẹ̀ tẹ́lẹ̀ dọ̀tun.

Àtẹ̀jáde ọ̀hún tun sọ pé wọ́n ti ní kí àwọn iléeṣẹ́ tọ́rọ̀ kàn san owó ìtanràn tó bá ìkọ̀ọ́kan àwọn ẹ̀sùn tí wọ́n fi kàn wọ́n.