Burundi: Ìbẹ̀rù bojo gbilẹ̀ bí ẹ̀mí se sòfò sáájú ìdìbò

Ọmọ ogun Burundi Image copyright AFP
Àkọlé àwòrán Ètò àbò ti gbépọn si sáájú ìdìbò gbogbogbò l'ọ́ṣẹ̀ tó ń bọ̀

O kere tan eeyan mẹrindinlọgbọn lo padanu ẹmi wọn lẹyin ti awọn agbebọn kọlu abule kan ni apa iwo oorun ariwa orilẹede Burundi.

Eleyi ṣẹlẹ bi ibẹru-boju ṣe gbalẹ saaju idibo gbogbogbo nilẹ naa.

A gbọ pe awọn agbebọn naa wa lati orilẹede DR Congo tan wọn si ya bo ẹkun Cibitoke.

Awọn akọroyin sọpe o ṣeeṣe ki ipaniyan naa ni i se pẹlu eto idibo oṣẹ to n bọ.

Wọn ni eto idibo naa le jẹ ki aarẹ orilẹede naa wa lori aleefa di ọdun 2034.

Aarẹ Pierre Nkurunza ti n ṣe 'jọba orilẹede naa lati ọdun 2005 ti ogun abẹlẹ ti pari n'ilẹ naa.